Mo tọrọ àforíjì fún ìyà àti ìṣẹ́ tó ń bá àwọn ọmọ Naijiria fínra - Aisha Buhari

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Niajiria fun iya ati iṣẹ to n ba awọn ọmọ Naijiria finra labẹ iṣejọba aarẹ Buhari.

Iyawo aarẹ naa sọ ọrọ yii lati ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ ominira orilẹede Niajiria fun ọdun 2022 lasiko to n sọrọ ni ilu Abuja.

Aisha Buhari ni bi o tilẹ jẹpe ijọba aarẹ Buhari ko munadoko to bo ti yẹ, ohun fi asiko yii tọrọ aforiji lọwọ awọn eniyan lati dariji awọn.

''Ẹ gbadura ki alaafia jọba ni eto idibo ọdun 2023''

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣiṣẹ pọ ki orilẹede Naijiria le lọ siwaju.

‘’ Gbogbo wa lo ri bi owo Naijiria ṣe dẹnukọlẹ, ti ko si si owo jaburata fun awọn araalu, eleyii to mu ki iṣoro de ba eto ẹkọ, ilera ati igbayegbadun awọn eniyan ni Naijiria.’’

‘’Eleyii kọ mi lominu, ti mo si tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu.’’

‘’Mo rọ awọn eniyan lati gbadura fun eto idibo ti yoo waye ni ọdun to n bọ, ki alaafia le jọba kaakiri orilẹede Naijiria.’’

Bakan naa lo ni ki opin le de ba ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria, awọn araalu gbọdọ fi ọwọ so wọpọ pẹlu ileeṣẹ ọmọogun Naijiria.

Iyawo aarẹ tun gboriyin fun awọn ẹṣọ fun bi wọn ṣe n sa gbogbo ipa wọn lati ri pe opin de ba igbesunmọmi ni Naijiria.

Aisha Buhari fikun un pe ileeṣẹ iyawo aarẹ n gbiyanju lati pese ounjẹ ati iṣẹ fun awọn araalu, paapaa awọn obinrin ki iṣẹ le dinku.

Bakan naa lo ni ijọba gbọdọ mu ọrọ iṣẹ agbẹ ni ọkunkun dun, ki ebi ati iṣẹ le dikun ni Naijiria.