Ọmọ ọdún mẹ́wàá dàwátì, wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú gọ́tà ní Ibadan
Ọmọ ọdún mẹ́wàá dàwátì, wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú gọ́tà ní Ibadan

Gbogbo abiyamọ ayé a ò ní fojú sunkún ọmọ.
Níṣe ni ọkàn òbí Ayoola Daniel gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe bá òkú ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́wàá nínú gọ́tà kan tí kò jìnà sí ilé tí wọ́n ń gbé ní agbègbè Wakajaye ní ìlú Ibadan.
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí àwọn òbí Ayoola láti gbọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ wọn, bàbá rẹ̀ ní ọjọ́ Ajé ni Ayoola ṣàdédé di àwátì.
Micheal Ayoola tó jẹ́ bàbá Daniel Ayoola ní aago méjì ní Ayoola ni máa ń dé láti ilé ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn nígbà tí àwọn kò rí ọmọ àwọn kó dé lásìkò.
Ó ní èyí ló mú kí òun àti ìyá ọmọ náà kó ẹsẹ̀ sọ́nà láti gba ilé ẹ̀kọ́ Wakajaye Community School lọ láti mọ ìdí tí ọmọ àwọn kò fi tíì délé lásìkò tó máa ń délé.
Micheal ṣàlàyé pé láti ọjọ́ Ajé náà ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá kó tó di wí pá àwọn ènìyàn kan wá sọ fún àwọn wí pé wọ́n ti rí ọmọ náà ní ẹ̀gbẹ́ ilé àwọn.
Ó ní àmọ́ òkú ọmọ ni àwọn rí nígbà tí àwọn máa fi dé ibẹ̀.
Wọ́n ní àgbàrá ojò ló wọ́ òkú ọmọ mi dé ibi tí a ti ba


Micheal tẹ̀síwájú pé ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn nígbà tí òun bá òkú ọmọ òun nínú gọ́tà tí àwọn ti ri nítorí gbogbo ibẹ̀ ni àwọn ti wá ṣíwájú.
Ó fi kun pé yàtọ̀ sí ilé iṣẹ́ rédíò, gbogbo ilé ilẹ̀ àti odò tó wà ní agbègbè àwọn ni àwọn ti wá ọmọ náà dé láti ọjọ́ Ajé tí àwọn kò rí nílé.
“Àwọn ará àdúgbò ló pè mí wí pé wọ́n rí òkú ọmọ mi nínú gọ́tà kan ní ẹ̀gbẹ́ ilé wá.”
“Nígbà tí mo débẹ̀, ó yà mi lẹ́nu pé ọmọ ọdún mẹ́wàá le gba ibẹ̀ nítorí ibẹ̀ ṣe tóóró gan.”
Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án mìíràn tún dàwátì
Yàtọ̀ sí Daniel Ayoola, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án mìíràn, Muhiba Kareem tó jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Wakajaye Community School náà tún ti di àwátì ní àná ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án.
Ìyá Muhiba, Kemi Kareem òun kò ri kí ọmọ òun náà padà sílé lẹ́yìn tó jáde nílé ẹ̀kọ́.
Kemi ní láti àná ọ̀hún ni òun ti ń wá ọmọ òun ṣùgbọ́n tí òun kò ì tíì gbúròó rẹ̀ rárá.
Kemi ṣàlàyé pé màmá àgbà tí Muhiba ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní Wakajaye ló pe òun pé àwọn kò rí ọmọ òun mọ́.
Ó ní lẹ́sẹ̀ kan ni òun kúrò ní Oje tí òun ń gbé tá àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá ọmọ náà ṣùgbọ́n àwọn kò ì tíì rí àpadàbọ̀ rẹ̀ títí di àsìkò tí a fi ń kó ìròyìn yìí jọ.
Ó fi kun pé nígbà tí òun dé ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì, ohun tí wọ́n sọ fún òun ni pé àwọn kò ri láti àná tí wọ́n ti kúrò ní ilé ẹ̀kọ́.
Ó ní òun ti lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Monatan.

Nígbà tí ikọ̀ ìròyìn BBC Yorùbá kàn sí ilé ẹ̀kọ́ Wakajaye ní nǹkan bí ago mẹ́wàá òwúrọ̀ yìí, kò sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kankan ní ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́.
Bákan náà ni àwọn olùkọ́ tó fi mọ́ olùkọ́ àgbà kò sí níbẹ̀ nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Gbogbo ìgbìyàn jú BBC Yorùbá láti kan sì agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo láti gbọ́ tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ìròyìn yìí ló já sí pàbó.












