Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Ebola àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn náà

Ebola

Oríṣun àwòrán, AFP

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Africa, CDC, ti sọ pe oun ti n ṣeto lati jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ apoogun oyinbo, to ti ṣe abẹrẹ ajẹsara to ṣe e ṣe ko koju ẹda aarun Ebola tuntun, Sudan Strain.

Oludari ajọ CDC, Dokita Ouma Ogwell, sọ ni Ọjọbọ pe ti awọn ba fi ṣe aṣeyọri lori igbesẹ naa, ni kiakia ni awọn yoo bẹrẹ lilo abẹrẹ naa fun itọju pajawiri ni Uganda.

Lọwọlọwọ, o ti pe eeyan mọkanlelọgbọn to ni ẹda aarun Ebola, Sudan strain naa, ti mẹfa lara wọn si ti ku ni Uganda.

Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa sọ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ilera to ko aarun naa wa bayii.

Arun wo ni wọn n pe ni Ebola?

Ebola jẹ arun buburu kan to maa n mu iba lọwọ, pẹlu ara riro.

Yoo maa rẹ ẹni to ba ni arun naa, bẹẹ si ni irufẹ ẹni bẹẹ, ọna ọfun yoo maa dun un.

Ti arun ọhun ba ti wọ eeyan lara, irufẹ ẹni bẹẹ yoo maa bi, bẹẹ si ni yoo maa ya igbẹ gburu.

Nigba miran ẹwẹ, ẹjẹ le maa jade lara ẹni to ba ni arun Ebola.

Bawo ni Ebola ṣe maa n tan kalẹ?

Ara ẹranko to ti ni arun naa tẹlẹ lo ti maa n ran eeyan, amọ ara ẹran igbẹ ti awọn eeyan n jẹ ni arun ọhun sodo si julọ.

Lati ibẹ lọ o le ran awọn ẹlomiran nipasẹ omi ara bii ẹjẹ, itọ́, eebi, atọ ọṃkunrin tabi ti obinrin, igbọnsẹ ati ooru.

Iwadii ijinlẹ ti fi han pe arun ọhun ṣi le wa ninu atọ ọkunrin lẹyin to ba ti gbawosan tan.

Bi o ṣe le dabo bo ara rẹ lọwọ Ebola

Ọna kan gboogi lati daabo bo ara ẹni lọwọ Ebola ni lati ṣọra fun ẹni to ba ti ni arun naa lara.

Maṣe bọwọ pẹlu ẹni to ba ni arun naa rara, fifọ ọwọ ẹni pẹlu omi ati ọṣẹ naa ṣe pataki.

Awọn oṣiṣẹ eto ilera gbọdọ wọn aṣọ atawọn ohun idaabo bo ara ẹni miran ti wọn ba fẹ ṣe itọju alaarun Ebola.