Owó ilé là pé owó táa fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá kìí ṣé mẹ́numọ́- PDP

Oríṣun àwòrán, Official Peoples Democratic Party (PDP) Nigeria
Igbimọ Amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ti ṣalaye idi ti ẹgbẹ fi fun awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa ni owo to le ni ọgọrun miliọnu Naira.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita,wọn ni owo tawọn fun awọn ọmọ ẹgbẹ yi kii ṣe owo mẹnumọ bi kii ṣe pe owo ile lawọn san fun wọn.
Wọn ni owo yi wa ni ibamu pẹlu ilana ẹgbẹ eyi to faaye gba ki wọn san owo ile awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ati awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ miran.
Esi ti wọn tori rẹ mu alaye yi wa ko ṣẹyin iroyin to gbode pe owo mẹnumọ ni wọn san fawọn ọmọ ẹgbẹ yi ki wọn baa ma sọrọ soke lori owo fọọmu to le ni biliọnu mẹẹdogun ti wọn ṣapapin rẹ.
Gẹgẹ baa ṣe ri ka ninu atẹjade ti Debo Ologunagba,akọwe ipolongo ẹgbẹ fi sita lorukọ igbimọ amuṣẹya, ''PDP ko san owo kankan fawọn ọmọ igbimọ amuṣẹya lowo abẹtẹlẹ abi tori nkan mii''
O fi kun pe ''a ṣe ayẹwo finifin kaa to san owo ile yi ati pe o wa ni ibamu pẹlu ajẹmnu ati ẹt mii fawọn ọmọ ẹgbẹ ati eekan inu ẹgbẹ''
Akọwe ipolongo ẹgbẹ yi tẹsiwaju pe iroyin kan ti ileeṣẹ iwe iroyin kan gbe jade lo da wahala sil nipa pe o gbe ayederu iroyin jade.
''iroyin ofege ti ileeṣẹ iroyin yi gbe jade pe owo abẹtẹlẹ ni owo ile taa san fawọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ wa jẹ''

Oríṣun àwòrán, Arapaja Oladejo Taofeek
Wahala abẹnu to n koju ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni Naijiria ti gba ọna mii yọ pẹlu bi iroyin ṣe gbode pe awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti ṣe apapin owo fọọmu ti wọn gba lọwọ awọn oludije sipo.
Awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya kan ninu ẹgbẹ PDP lo da owo naa to le ni ọgọrun miliọnu Naira pada ti ṣe ti n da owo pada si akoto ẹgbẹ.
Ko tan sibẹ, wọn tun fi lẹta pẹlu owo ti wọn da pada ti wọn si ṣalaye sinu rẹ pe awọn ko mọ nipa owo ti o wa lati ọdọ akapo ẹgbẹ tori naa awọn fẹ da owo naa pada.
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn ọmọ ẹgbẹ PDP bi Ambassador Taofeek Arapaja to jẹ igbakeji alaga apapọ ni iwọ oorun Guusu Naijiira ati alaga fagbegbe iwọ oorun Guusu Naijiria Olasoji Adagunodo ti n ṣafihan iwe ti wọn fi da owo pada.
Ninu iwe ti Arapaja kọ si alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu, o ni iroyin to gbode pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ti ba wọn pin ninu owo to to biliọnu mẹẹdogun owo fọọmu lo mu ki oun lo yẹ apo aka-n-ti oun wo.
O ni lẹyin ti oun wo iye to wọle si akoto owo oun, loun wa ri wi pe wọn san miliọnu mẹrindinlọgbọn Naira kan wọle lati ọdọ akapo owo ẹgbẹ.
O fi lẹta to fi sita yi sọ fun ẹgbẹ wi pe oun ti da owo naa pada.
Lẹta rẹ yi ko fi taratara yatọ si eyi tawọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa mii fi ṣalaye bawọn ko ṣe mọ nipa obitibiti owo yi ati pe ariwo to pọ lode wi pe awọn ti gbadọde lo mu kawọn da owo naa pada.

Oríṣun àwòrán, Olusoji Adagunodo
Kini yoo wa ṣẹlẹ lẹyin ti wọn da owo yi pada?
A ko le sọ pato boya iroyin ati ẹsun ajẹbanuyi yoo tunbọ fawọn to fẹ ki alaga ẹgbẹ Iyorchia kuro nipo lagbara si.
Laipẹ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan bi Gomina ipinlẹ Rivers Nyesom Wike ati seyi Makinde ti Oyo, ti n sọ pe ko yẹ ki Iyorchia Ayu ṣi wa lori ipo alaga ẹgbẹ.
Koda, awọn gomina naa ati awọn kan ko yọju sibi ifilọlẹ ipolongo ibo aAtiku Abubakar to waye l'Ọjọru.
A ko mọ boya eyi niṣe pẹlu ipinu wọn pe ayafi ki Iyorchia Ayu kuro lori ipo gẹgẹ bi alaga.
Amọ ṣa bayi ti wọn ti n da owo pada, o ṣeeṣe ki o jẹ pe ibẹrẹ ọna ti wọn yoo fi yẹ aga nidi Iyorchia Ayu ni wọnfẹ gunle yi.
Bi iwadii ba lọ to bọ, o ṣeeṣe ki wọn ni kiAyu wa ṣalaye idi to fi ni ki wọn san aduru owo yi sakoto awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ.












