Àwọn ajagunfẹ̀yìntì ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí owó oṣù àti àjẹmọ́nú wọn

Àwòrán àwọn ajagufẹ̀yìntì tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn

Àwọn ajagunfẹ̀yìntì kaakiri orilẹ ede Naijiria ti bẹrẹ ifẹhonuhan ni ẹnu ọna ilé isẹ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria iyẹn ship house to wa niluu Abuja.

Ohun ti wọn n ṣe ifẹhonuhan le lori ni bi awọn alakoso ile-isẹ ọmọ ogun se kọ̀ lati san owó eto aabo ti ijọba apapọ ni ki wọn san wọn.

Ètò ifẹhonuhan naa lo bẹrẹ ni deede aago mẹjọ owurọ ọjọ Aje, ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an, bi o tilẹ jẹ pe ojo fẹ di ifẹhonuhan ọhun lọwọ, sibẹ awọn ajagunfẹyinti ọhun fi aake kọri lati duro si ẹnu ọna ile-isẹ ọmọ ogun.

Wọn pinnu wi pe ti awọn ko ba ri owó awọn gba, àwọn ko ni fi ẹnu ọna ile-isẹ ologun naa silẹ.

Pupọ ninu awọn ajagunfẹ̀yìntì naa ni wọn gbe ìbùsùn lọ́wọ́ ,ohun ìdáná ati awọn àkọlé orisirisi lọwọ́.

Lara awọn ohun ti wọn kọ si akọle ọhun ni "Ẹ se atunse si eto owo osu ti ẹ ń san, ki aparo kan maa ṣe ga ju omiran lọ."

Ni osu kiini ọdun yii ni awọn ajagunfẹ̀yìntì naa ti kọkọ ṣe ifẹhonuhan ni ile-isẹ to n mojuto eto inawo niluu Abuja latari owó osu mẹrinlelogun ti ijọba apapọ ko san fun wọn.

Àwòrán àwọn ajagufẹ̀yìntì tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn
Àwòrán àwọn ajagufẹ̀yìntì tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn
Àwòrán àwọn ajagufẹ̀yìntì tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn

Agbẹnusọ fun awọn ajagunfẹ̀yìntì ọhun, Abiodun Durowaiye-Herberts sọ pe awọn ti setan lati sún si ile-iṣẹ ajọ ọmọ ogun titi ti wọn yoo fi dawọn lohun.

O tẹsiwaju pe awọn ni aya , ọmọ ati awọn opó fun awọn ti wọn padanu ẹ̀mí wọn loju ogun lasiko ti wọn n ba awọn ikọ Boko Hraam wọya ijakadi.

Wọn wa rọ minisita fún eto aabo, Bashir Magashi lati san ajẹmọnu owo naa eyi ti aarẹ Muhammadu Buhari ti fọwọsi lati san fún wọn .