Sͅé lóòtóͅ ni iléeͅjóͅ pàseͅ kí Obi-Datty má se ìpolongo ìdìbò ní Lekki Toll-gate?

Oríṣun àwòrán, PETER OBI/TWITTER
Ajoͅ awoͅn agbeͅjoͅro fun oludije sipo aare legbe oselu Labour Party, Peter Obi ti ni ko si otitoͅ ninu iroyin pe ileeͅjoͅ pasͅeͅ fun awoͅn lati ma se ipolongo ni Lekki Tollgate ni ipinle Eko.
Oͅjoͅ Kini, Osͅu Keͅwaa ni ipolongo idibo naa yeͅ ko waye.
Iroyin to n kaakiri ni pe ileeͅjoͅ kan nipinleͅ Eko pasͅeͅ fun eͅgbeͅ ati awoͅn ololufeͅ woͅn lati masͅe korapoͅ si opopona Lekki Toll gate. Ohun ti woͅn le e sͅe nikan ni lati rin koͅja nibeͅ.
O yeͅ ko le ni milioͅnu meͅrin awoͅn oͅdoͅ ti yoo pejo po si ibi Ipolongo idibo naa.
Amoͅ agbeͅnusoͅ fun awoͅn agbejͅoro eͅgbeͅ osͅelu Labour ninu ateͅjade ni kii sͅe ohun ti adajoͅ soͅ niyeͅn.
O ni asͅeͅ eͅgbeͅ ni ki eͅgbeͅ osͅelu labour sͅe iwoͅde ni agbegbe Lekki, Ikeja, Surulere ati Festac.
Bakan naa ni o ni ileeͅjoͅ gba woͅn laaye lati sͅe iwoͅde koͅja nibeͅ, amoͅ ko gboͅdoͅ jeͅ ibi apejoͅpoͅ won.
Kilo de ti awoͅn agbeͅjoͅro gbe Peter Obi loͅ si ileeͅjoͅ?
Awoͅn agbeͅjoͅro bii meͅwaa, ti Adedotun Ajulo sͅe agbateͅru fun gbe eͅgbeͅ osͅelu Labour Party loͅ si ileeͅjoͅ lori eͅsun pe woͅn ko gboͅdoͅ loͅ Lekki Toll-gate fun iwode kankan.
Awoͅn agbeͅjoͅro naa ni eͅgbeͅ osͅelu Labour Party feͅ da omi alaafia ipinleͅ Eko ru ni, eleyii ti yoo da wahala bii iwoͅde Endsars sileͅ.
Iwoͅde naa to yeͅ ko waye ni Oͅjoͅ Kini, Osͅu Keͅwaa oͅdun 2022, amoͅ woͅn tako eleyii.
Woͅn ni Osͅu Keͅwaa, oͅdun 2020 naa ni isͅeͅleͅ ENDSARS waye nigba naa lohun, ti o si fa rogbodiyan kaakiri orileͅede Naijiria.
Kini adajoͅ soͅ lori ipolongo Obi-Datti ni Lekki-Toll-gate?
Geͅgeͅbi ateͅjade to wa ni ita sͅe soͅ, adajoͅ woͅgile ipe fun ki ipolongo ma waye ni ipinleͅ Eko.
Bakan naa ni adajoͅ ni ko si otitoͅ kankan ninu iroyin pe ipolongo idibo naa yoo dabi ti ENDSARS.
O ni rogbodiyan beͅ sileͅ nigba ti awoͅn ologun sͅekoͅlu si awoͅn afeͅhoͅnuhan naa ni Ogunjoͅ, Osͅu Keͅwaa, oͅdun 2020.
Adajoͅ ni iwoͅde Endsars ko ni nkankan sͅe peͅlu ipolongo idibo eͅgbeͅ osͅelu ti woͅn ni eͅtoͅ si labeͅ ofin lati sͅe.
Eͅweͅ, Ajoͅ eleto idibo ni Naijiria, INEC ti fun awoͅn eͅgbeͅ oselu ni asͅeͅ lati beͅreͅ ipolongo idibo sͅaaju eto idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Oͅjoͅ Karundinloͅgboͅn, Osͅu Keji, Oͅdun 2023.












