'Àwọn tó pa Bamise nínú BRT ba ojú ara àbúrò mi jẹ́ yánkan-yànkan'

Oríṣun àwòrán, Bamise Ayanwola
Ẹgbọn ọdọbirin ti wọn ni awakọ BRT ṣekupa l’Eko, iyẹn Oluwabamise Ayanwola, ti sọ fun ile ẹjọ to n gbọ ẹsun naa pe wọn ti ba oju ara oloogbe naa jẹ lasiko ti awọn ọlọpaa yoo fi ṣawari oku rẹ.
Ibatan rẹ ọhun, Abegunde Ayanwola lo sọ ọrọ naa lasiko to wa jẹri niwaju ile ẹjọ tako awakọ BRT ti wọn ni o pa ọdọbirin naa, Andrew Nice Ominikoron.
Andrew Nice yii ni wọn fẹsun kan pe o ba oloogbe naa lopọ pẹlu ipa, to tun gba ẹmi rẹ lẹyin naa.
O tun n koju ẹsun ibalopọ ero ọkọ mii, iyẹn Maryjane Odezelu.
Ohun to ṣẹlẹ nile ẹjọ
O ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2022 yii ni Bamise kuro nile lati ṣabẹwo si ọkan lara awọn ẹgbọn rẹ, amọ ko de ibi to n lọ, eyii lo mu ki wọn bẹrẹ si n wa.
Ọkan lara awọn ọrẹ Bamise lo ṣalaye fun awọn mọlẹbi rẹ pe o n ba oun sọrọ jolu opo WhatsApp pe oun wọ inu ọkọ ero BTR, amọ pe ẹru n ba oun ninu ọkọ ero naa nitori awọn nnkan ti oun fura si lẹyin ti gbogbo awọn ero ọkọ naa ti sọto si ku oun nikan sinu rẹ pẹlu awakọ.
Abegunde ṣalaye pe Bamise ati ọrẹ rẹ ọhun fi ohun ranṣẹ si ara wọn lori WhatsApp, eredi ree ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lọ ṣe ọfintoto bi oloogbe naa ṣe rin ni ileeṣẹ to n bojuto BRT l’Eko.
O fi kun pe ileeṣẹ BRT bere aṣẹ lati ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn to fun awọn laṣẹ lati wo aworan ori CCTV inu BRT naa.
Gẹgẹ bii ohun ti Abegunde sọ, awọn ọlọpaa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa, eyii to mu ki a wọn kọ lẹta si ọọfisi ileeṣẹ to n ṣakoso BRT l’Eko, LAMATA ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun.
O ni lẹyin oniruru igbinyaju ni wọn ri oku aburo oun nile igbokusi kan lọjọ keje, oṣu Kẹta, lẹyin ti ẹnikan dari awọn si agọ ọlọpaa to wa ni Ebute Ero.
Nigba ti agbẹjọro afurasi bere lọwọ ẹgbọn Bamise ohun to n gbiyanju lati sọ nigba to sọ pe wọn ti ba oju ara oloogbe naa jẹ.
Pẹlu omije loju, o ni “’Virgin’ ni ọmọ naa, ti awọn ọkunrin bii meji si mẹta si ba lopọ, ṣe ẹ fẹ ki n maa ṣalaye bi oju ara rẹ sẹ ri ni? Rara o! Mi o le ṣalaye.”
Adajọ gbọnmu fun agbẹjọro afurasi
Ṣaaju ni agbẹjọro afurasi, Ọgbẹni Omotubora tọrọ afọriji lọwọ adajọ pe oun pẹ de ile ẹjọ naa ni ijoko to waye kẹyin, o ni sunkẹrẹ-fakerẹ ọkọ to maa n waye lagbegbe Ikorodu lo ṣokunfa rẹ.
Adajọ Sherifat Sonaike wa fun lesi pe oun ti fun ẹlomiran ni ipo rẹ.
O kere tan, agbẹjọro naa ti kuna lati yọju si ijoko marun un ọtọtọ.
Adajọ sọ fun pe irufẹ iwa bẹẹ tumọ si pe ko bọwọ fun ile ẹjọ, lẹyin naa lo sun igbẹjọ naa si ọjọ karundinlọgbọn ati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwa, ọdun 2022.












