Oyetola kò ní àṣẹ láti díje gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní Ọsun – Iléẹjọ gíga

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ileẹjọ giga ni ilu Abuja ti ni gomina Isiaka Oyetola ati igbakeji rẹ, Benedict Alabi ko laṣẹ labẹ ofin lati dije du ipo gomina ni ipinlẹ Osun.
Ileẹjọ ni igbesẹ naa ko ṣẹyin bi gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni to tun di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC ṣe buwọlu idije wọn.
Ileẹjọ ni eyi tako ofin orilẹede Naijiria nitori labẹ ofin Buni kuna lati di ipo meji mu.
‘’Buni ko laṣẹ lati buwọlu iyansipo Oyetola’’
Ni Ọjọ Keje, Osu kẹrin, ọdun 2022 ni Arakunrin Ogunwumiju (SAN) fi ẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC nipa iyansipo gomina ipinlẹ Osun, Isiaka Oyetola gẹgẹ bi oludije sipo gomina nipinlẹ naa, ti Alaga ẹgbẹ buwọ lu.
Agbẹjọrọ naa ni Alaga ẹgbẹ ko lee di ipo meji mu labẹ abala ofin 285(14) (c), ti ọdun 1999.
Amọ awọn agbẹjọro gomina naa ti Muyiwa Atoyebi SAN ṣe adari fun ni ko si ohun to buru ninu ohun ti Buni ṣe nitori o ni ẹtọ ni abẹ abala ofin 183.
Amọ adajọ ni iyansipo Oyetola ko lẹṣẹ nilẹ nitori Buni di ipo gomina ipinlẹ Yobe mu, to si tun di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.
Ẹyin temi ẹ ma mikan, ko si ewu – Oyetola
Ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ti sọ fun awọn eniyan rẹ lati fi ọkan balẹ nitori mimi kan ko lee mi awọn.
Eyi ko ṣẹyin aṣẹ ileẹjọ giga ni ilu Abuja to ni ko ni aṣẹ lati dije dupo gomina ni saa keji.
Oyetola ni awọn n gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ fun agbeyẹwọ idajọ ọhun.
O ni gbogbo igbiyanju awọn alatako ni lati doju igbẹjọ to n lọ lọwọ ni ile ẹjọ to n gbẹjọ lori idibo bolẹ.












