Ìwọde forí ṣọ́npọ́n! Wo ìṣẹ̀lẹ̀ “4 million man march” àwọn alatilẹyin Peter Obi bó ṣe rí l’Eko

Awọn alatilẹyin oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, ti wọn maa n pe ara wọn ni "Obidient" ti ṣe iwọde niluu Eko.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede pe miliọnu mẹrin eeyan lawọn n reti nibi iwọde naa, ati pe iloro Lekki Toll Gate ni iwọde naa yoo ti waye.
Amọ lẹyin ikede naa ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe awọn ko ni gba ki iwọde kankan waye ni Lekki Toll Gate.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Benjamin Hundeyin fi lede, o ni “O ṣe pataki lati jẹ ki awọn araalu mọ pe a ko ni gba ki iwọde kankan waye ni Lekki Toll Gate.”
“Ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki ẹnikẹni maṣe ṣe iwọde kankan ni Toll Gate ọhun.”
“Eyii jẹ ọna lati pa ẹmi ati dukia awọn eeyan mọ.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ohun to ṣẹlẹ ni Toll Gate
Lasiko ti ikọ ileeṣẹ iroyin BBC ṣabẹwo si ẹnu iloro Lekki Toll Gate naa, wamu-wamu ni awọn ọlọpaa duro digbi sibẹ pẹlu ibọn lọwọ wọn.
A ko foju ganni oluwọde kankan ni Toll Gate naa, ayafi awọn ọlọpaa to wa nibẹ.

Amọ ṣa, lara awọn eeyan naa ṣe iwọde lawọn agbegbe mii ni Lekki, wọn tun ṣe iwọde ni Surulere, Ikeja ati Festac.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni iwọde EndSARS bẹrẹ, ki iwọde naa to gbọna mii yọ ni iloro Lekki Toll Gate yii logunjọ oṣu kan naa, nini ọpọ ẹmi ti sọnu.
Lati asiko naa wa ni ijọba ipinlẹ Eko ti kọ ki ẹnikẹmi maa ṣe iwọde ni iloro naa.














