Wo àwọn èèyàn tó ná ọ̀pọ̀ owó, ṣe iṣẹ́ abẹ bíi igba láti di ẹranko

Body modifications

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Daily Mail UK

    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, Broadcast Journalist, BBC Yoruba
    • Reporting from, Lagos

Awọn onimọ ijinlẹ gbagbọ pe nnkan ẹyọ kan ko le maa wu eeyan ni gbogbo igba, idi ree ti eeyan fi maa n jẹ oniruru ounjẹ lojojumọ.

Bakan naa ni awọn eeyan maa n paarọ aṣọ, bata, ile tabi adugbo ti wọn n gbe, awọn mii ẹwẹ a maa paarọ ololufẹ wọn ti wọn a si sọ pe ko rọrun lati maa jẹ ounjẹ kan naa ni gbogbo igba.

Amọ n jẹ o ṣeeṣe ki eeyan paarọ bi awọ, ẹya ara tabi irisi rẹ ṣe ri?

Ibeere nla leyi jẹ, ibeere yii kan naa lo si sokunfa bawọn eeyan mẹrin wọnyi, ti wọn ni wọn ko nifẹ si bi ẹya ara wọn ṣe ri, se tun ara wọn da.

Amọ abamọ nla ni eyi jẹ fun wọn, to si jẹ pe ẹtẹ lo ba de fun awọn kan ninu wọn ni ikẹyin.

BBC Yoruba wa se akojọpọ eeyan mẹrin pere ninu awọn eeyan to tun ara wọn da yatọ si bi Ẹlẹda se da wọn.

Wo eeyan mẹrin to tun ẹya ara wọn da:

Dennis Avner - O ṣe iṣ abẹ mẹrinla lati sọ ara rẹ di ẹkun

Dennis Avner

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dennis Avner, ti apele rẹ n jẹ ‘Stalking cat’ ni wọn bi niluu Michigan, nilẹ Amẹrika, lọdun 1958.

O ṣe iṣẹ abẹ nigba mẹrinla lati yi irisi rẹ pada si ti ẹkun, eyii to mu ko gba ami ẹyẹ agbaye fun ẹni to ṣiṣẹ abẹ julọ lọna ati da bii ẹranko.

Avner kọkọ ṣiṣẹ ologun ofurufu fun ọdun diẹ ko to kuro nibẹ lọdun 1981, ko pẹ lẹyin naa to bẹrẹ si n ya ‘tatoo’ si ara, ko fi le da bii ẹkun.

Ọdun 2012 ni wọn ri oku rẹ ninu gareji rẹ lẹyin ọsẹ kan to ti jade laye, iroyin ni ṣe lo pa ara rẹ.

Tiamat Legion Medusa - lo ọpọ asiko ninu igbo, na £61,000 lati se isẹ abẹ ko le dabi ejo

Tiamat Legion Medusa

Oríṣun àwòrán, Tiamat Legion Medusa

Richard Hernandez ni orukọ abisọ ọkunrin naa, oṣiṣẹ ile ifowopamọ si ni ní ibẹrẹ ayẹ rẹ.

Ṣaaju ni awọn obi rẹ ti kọkọ pinya, ti ko si gbe lọdọ eyikeyi ninu awọn mejeji, eyi to mu ko maa lo ọpọ akoko ninu igbo pẹlu awọn ẹranko afayafa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ akoko to maa n lo ninu igbo yii mu ko fẹran ejo pupọ, eyii to mu ko ya ọpọ tattoo ati iṣẹ abẹ lati da bii ejo.

Ọkunrin naa to n fi ilu Los Angeles ṣe ibugbe, na owo ti iye to £61,000 lati da bii ejo.

Lẹyin to di gbajumọ tan, o ṣiṣẹ abẹ lati sọ ara rẹ di obinrin, o si kede pe oun yoo ge nnkan ọmọkunrin oun sọnu.

Ni bayii , Tiamat ti lugbadi arun kogboogun HIV, amọ o ṣi n ba iṣẹ abẹ rẹ lati di ejo lọ.

Richard Hernandez si ti kede pe iṣẹ abẹ naa yoo pari titi ọdun 2025.

Pixee Fox – na £500,000 lati se isẹ abẹ nigba igba ko le sọ ara rẹ di ‘cartoon’

Pixee Fox - The Living Cartoon

Oríṣun àwòrán, Pixee Fox - The Living Cartoon

Obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ti ṣiṣẹ abẹ nigba igba, o si ti na owo ti iye rẹ to £500,000 fun awọn iṣẹ abẹ naa.

Ohun ti obinrin naa ṣe ni pe o yọ egungun ẹgbẹ rẹ mẹfa, ki bebere idi rẹ le kere lọna ati farajọ ‘cartoon.’

María José Cristerna - The Vampire Woman

María José Cristerna

Oríṣun àwòrán, @renmusb1

Iṣẹ agbẹjọro ni obinrin yii n ṣe, o si tun jẹ oniṣowo pẹlu.

Ọdun 1967 ni wọn bi niluu Guadalajara, ni Mexico.

Nnkan to mu ki irawọ obinrin naa tan, ko ṣẹyin awọn iṣẹ abẹ to ṣe atawọn tattoo to ya si ara rẹ lati yi ara rẹ pada.

O ni oun gbe igbesẹ naa lọna ati ṣe itaniji fun awọn eeyan lodi si iwa ipa si awọn obinrin ninu ile.