Ejòlá pa obìnrin kan, gbemì ní odidi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obìnrin kan ní orílẹ̀ èdè Indonesia ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ ejòlá, tí ejòlá náà sì tún gbemì ní odidi.
Ìròyìn ní Jahrah ẹni àádọ́ta ọdún ló jẹ́ àgbẹ̀ tó máa ń gbin rọ́bà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú nígbà tó lọ sí oko.
Nígbà tó di alẹ́ ọjọ́ náà tí àwọn ará ìlú kò rí ìpadàbọ̀ Jahrah láti oko tó lọ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wa ṣùgbọ́n tí gbogbo ìgbìyànjú já sì pàbó.
Ní ọjọ́ kejì ní àwọn ará ìlú rí ejòlá kan tí ikùn rẹ̀ tóbi púpọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ oko tí Jahrah lọ.
Èyí ló mú kí àwọn ará ìlú náà pa ejòlá náà tí wọ́n sì bá òkú Jahrah nínú ikùn ejòlá náà.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Betara Jambi, Harefa ní gbogbo ẹ̀yà Jahrah ló pé pérépéré nígbà tí wọ́n la ikùn ejòlá náà ṣùgbọ́n ẹ̀mí rẹ̀ ti lọ si.
Harefa ní ọkọ Jahrah sọ wí pé nígbà tí àwọn dé oko rọ́bà tó ti lálẹ́ ọjọ́ Àìkú, àwọn bá àwọn aṣọ rẹ̀ kan àtàwọn ohun èlò tó ń lò ní oko níbẹ̀ ni àwọn fi bẹ̀rẹ̀ sí ní wa nítorí òun nígbàgbọ́ pé nǹkan ti ṣẹlẹ̀ si ni.
Ó ní ejòlá ọ̀hún gùn ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínlógún ni àwọn ará ìlú pa lọ́jọ́ Ajé tí wọ́n sì bá òkú onbìnrin náà nínú rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kò wọ́ pọ̀, ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ejòlá yóò pa ènìyàn tí yóò sì gbemì lódidi ní orílẹ̀ èdè Indonesia.
Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé ní ọdún 2017 àti 2018 ní orílẹ̀ èdè Indonesia bákan náà.















