Kí ló fa 'gbas gbos' láàárín àwọn káńsílọ̀ àti alága ìjọba ìbílẹ̀ Ijebu East tí wọ́n fi ní kó lọ rọ́kún nílé

Wale Adedayo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Wale Adedayo

Àwọn káhúnsílọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ijebu East ti ní kí alága ìjọba ìbílẹ̀ náà, Wale Adedayo lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́ta ná fẹ́sùn wí pé ó ṣe owó ìlú kúmọkùmọ.

Àwọn káhúnsílọ̀ náà nínú lẹ́tà kan tí wọ́n fi léde ní onírúurú ẹ̀sùn ni àwọn rígbà pé alága náà ń ṣe owó ìjọba ìbílẹ̀ náà lọ́nà àìtọ́.

Lẹ́tà ọ̀hún tí olórí ọmọ ilé, Fasheyi Adesuji àtàwọn káhúnsílọ̀ mẹ́fà mìíràn buwọ́lu ní àwọn ẹ̀sùn mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n kà sí Adedayo lẹ́sẹ̀, tí àwọn ẹ̀sùn ọ̀hún sì nílò kí àwọn ṣe ìwádìí rẹ̀.

Wọ́n ní kí Adedayo kó gbogbo àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ìjọba ìbílẹ̀ náà tó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ fún igbákejì rẹ̀ kó sì yọjú níwájú ìjókòó àwọn ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹsàn-án fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.

Wọ́n ní oṣù mẹ́ta tí àwọn fún alága náà láti lọ rọ́kún nílé yóò fún àwọn láàyè láti ṣèwádìí rẹ̀ dáadáa.

Bí wọ́n ṣe ní kí Adedayo lọ rọ́kún nílé yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tó fẹ̀sùn kan gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun pé ó ṣe owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lọ́nà àìtọ́.

Ní nǹkan bíi ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni alága ìjọba ìbílẹ̀ náà fẹ̀sùn kan gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun pé ó ń gbé owó tó jẹ́ ti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gboko ibòmíràn.

Adedayo fẹ́sùn kàn pé láti bí ọdún méjì ni gómìnà Abiodun kò ti kó owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó ń wá láti ọdọ̀ ìjọba àpapọ̀ sí akoto àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Ó kọ lẹ́tà sí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ náà, Olusegun Osoba láti dá sí ọ̀rọ̀ ọ̀hún nítorí pé láti ọdún 2021 tí àwọn ti wọlé gẹ́gẹ́ bí alága, àwọn kò rí owó kankan tó ń wọlé láti ọdọ̀ ìjọba àpapọ̀.

Awọn alaga n dọbalẹ fun gomina ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ó tún fẹ̀sùn kàn pé bákan náà ni ọmọ ṣe ṣorí lásìkò ìṣèjọba Ibikunle Amosun gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ náà àti pé àwọn gómìnà ọ̀hún ń sọ wí pé àwọn ń ran àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà lọ́wọ́ ni.

Lẹ́yìn tí lẹ́tà tí Adedayo kọ ránṣẹ́ sí Osoba gba ìgboro, fídíò kan náà gba orí ayélujára tó ṣàfihàn bí Adedayo àtàwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kàndínlógún mìíràn ṣe lọ bẹ gómìnà Abiodun.

Fídíò náà ṣàfihàn bí àwọn alága náà ṣe ń dọ́bálẹ̀ níwájú Abiodun pé kó dáríji àwọn lórí lẹ́tà tí Adedayo kọ náà tí èyí sì fa awuyewuye láàárín àwọn ènìyàn.

Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Wale Adedayo lọ́rùn

Lára àwọn ẹ̀sùn tí àwọn káhúnsílọ̀ náà kà sí Wale Adedayo lọ́rùn ni pé:

  • ó gba mílíọ̀nù mẹ́rin náírà ní akoto ìjọba ìbílẹ̀ náà fún ṣíṣe ètò ìkúnpá fún àwọn ènìyàn ṣùgbọ́n tí ètò náà kò wáyé rárá.
  • Níná mílíọ̀nù méjì náírà ṣòfò lórí àyájọ́ ọdún Ìṣẹ̀ṣẹ̀ lọ́dún 2022.
  • Gbígba N260,000 àti N250,00 láti akoto ìjọba ìbílẹ̀ náà fún ìrànàjò afẹ́ fún alága àtàwọn ọ̀gá mìíràn nínú oṣù Kẹfà ọdún 2023.
  • Níná N426,000 fún ayẹyẹ ọdún Jigbo lọ́dún 2020 nígbà tí wọn kò ì tíì yàn wọ́n sí ọ̀fíìsì.
  • Níná N350,000 sí ayẹyẹ “Àwọn obìnrin nínú òṣèlú ní Ijebu East” lọ́dún 2022 àma tí wan ní wọn k]o kó owó náà fún àwọn obbìnrin náà.
  • Níná N350,000 àti N295,000 fún wẹ̀jẹwẹ̀mu níbi ètò ìṣílé nínú oṣù kẹrin ọdún 2023.
  • Níná N8.2m lórí àga ogún fún àwọn ilé ẹ̀kọ́.
  • Ogún mílíọ̀nù náírà àti mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún náírà tó ń wà láti akoto ìjọba ìpínlẹ̀ kò wọ akoto ìjọba ìbílẹ̀.
  • Gbígba owọ lọ́wa àwọn ọlọ́kadà lọ́nà àìtọ́.

Àjọ DSS ti fi Wale Adedayo tí wọ́n fi òfin de ni ìpínlè ogún sínú ìgbèkùn wọn

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní nǹkan bí aago mokanla òwúrò ọjọ́ etí ni àwọn Ẹṣo Alaabo DSS tí ó wà ní òkè Mosan Abeokuta tí fi Alaga náà sì ahamo wọn.

Akoroyin BBC news Yoruba ti o wa pẹ̀lú amugbalegbe àti dereba fún alaga ijoba ibile Ìjẹ̀bú East náà ni Olú ile Ìṣe Àjọ DSS náà tí ó wà ní òkè Mosan Abeokuta ròyìn pé inú ahamo ọgbà DSS náà ni Ogbeni Wale Adedayo wá títí di ń kan bíi agogo mẹsan asale kí ó tó di pé àwọn Ẹṣo DSS náà sọ pe inú ahamo náà ni alaga tí wọ́n fi òfin de òun yóò wà títí di ọjọ abameta.

Gẹ́gẹ́ àlàyé tí Ogbeni wálé Adedayo ṣe fún akoroyin BBC news Yoruba kí ó tó di pé wọ́n fi sínú ìgbèkùn àwọn DSS náà, ó ní nise ni àjọ ọ̀hún ranṣẹ pé òun láti wá yọjú sí wọn ní ilé ìṣe wọn tí ó wà ní òkè Mosan Abeokuta láti Ìjẹ̀bú ìfẹ́ tí òun wà.

Gbogbo igbiyanju láti bá oga agba Ẹṣo DSS náà sọ̀rọ̀ ni ó já sí pàbó.

Ọjọ́bo, ọjọ́ konkonlelogbon, oṣù kẹjọ ọdún 2023 ni méje nínú àwọn mokanla nínú àwọn asofin ìjọba ìbílẹ̀ Ìjẹ̀bú East náà fi òfin de Ogbeni wálé Adedayo lórí ẹ̀sùn ajebanu.

Ogbeni wálé Adedayo ni alaga ijoba ibile Ìjẹ̀bú East tí ó kó lẹta sì asiwaju àti Gómìnà ipinlẹ Ogun tẹ́lẹ̀ rí, Aremo Olusegun Osoba látàrí owó isaporo tí ó jẹ ti ijoba ibile ti gómìnà ipinle Ogun Ọmọba Dapo Abiodun kò sàn fún ìjọba ìbílẹ̀ Ogun ti o wa ni Ìpínlẹ̀ Ògùn láti bíi ọdún méjì sẹyin.