Ta ni Ọ̀gágun Brice Oligui Nguema adári tí ológun Gabon gbé ìjọba fún báyìí?

Ọgagun Brice

Oríṣun àwòrán, AFP

Lẹyin ti wọn le aarẹ Gabo, Ali Bongo kuro lori oye, fọnran Ọgagun Brice Oligui Nguema ti awọn ologun n gbe soke ṣe iwọde kaakiri ilu ni a ri ti wọn n yọ ṣẹṣẹ ti wọn si n kọrin pe “Oligui, Aarẹ! Oligui, Aarẹ!”.

Daju daju, Ọgagun ẹni ọdun mejidinlaadọta naa jọ pe ẹni ti awọn araalu fẹran ni pẹlu bi awọn ọmọ ogun rẹ ṣe n gbe e gẹ gẹ gẹ amọ fun awọn miran, adari ti wọn ko reti rẹ tẹlẹ ni.

Ni ọdun marun sẹyin, ko fi bẹẹ jẹ ẹni mimọ loju awọn eeyan Gabon to si jẹ pe o ti lo ọdun mẹwaa lẹyin odi ilu lẹyin ti wọn ti gba a sẹgbẹ kuro laarin awọn to sunmọ ẹbi Bongo, iyẹn ẹbi to jẹ pe titi di Ọjọru ọsẹ yii, awọn ni wọn dari ijọba orilẹede Gabo fun ọdun to fẹrẹẹ to mẹrindinlọgọta.

Nigba ti Ọgagun Nguema pada de, o goke agba de ipo to ga gan lai pariwo. Nibi, o fi gbogbo ọjọ rẹ ṣe amojuto ijọba aarẹ Ali Bongo.

Ọgagun Brice

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nibo ni Ọgagun Nguema ti wa?

Alagbara ilẹ Gabon yii ni wọn bi ni ileto Gabon kan to n jẹ Haut-Ogooué. Agbegbe yii jẹ ibi ti idile Bongo ti lagbara gan koda ti awọn kan n sọ pe Ọgagun Nguema jẹ ibatan awọn Bongo.

Nguema tọpasẹ baba rẹ to si yan iṣẹ ologun laayo. Nigba to ṣi wa lewe, o dara pọ mọ ikọ alaabo alagbara kan ni Gabon, lẹyin to ti kọkọ gba ẹkọ ni ile ẹkọ ologun ilumọọka kan ni Morocco, Meknes Royal Military Academy.

Ọdọkunrin ologun to ni ifẹ iṣẹ yii tete di ẹni ti awọn ikọ ologun n foju si lara ti wọn si fẹran rẹ, lo ba di oluranlọwọ fun aarẹ igba naa, Omar Bongo, ẹni to jẹ baba Ali Bongo.

Wọn maa n sọ pe Ọgagun Nguema sunmọ Omar Bongo gidi gan – o sin adari-apaṣẹwaa naa titi iku rẹ ni dun 2009.

“O jẹ ẹni ti wọn ko reti lati dari Gabon lakoko yii,” alalaye kan nipa eto oṣelu Afirika to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ Amber Advisers, Edwige Sorgho-Depagne sọ fun BBC.

Ni ọọdunrun 2000, o jina rere si orilẹede naa fun igba diẹ... wọn tilẹ ti fẹẹ gbagbe rẹ.”

Nigba ti Ali Bongo gba ijọba lẹyin baba rẹ lọdun 2009, wọn le Ọgagun Nguema kuro lẹnu iṣẹ rẹ.

O bẹrẹ ohun ti awọn oniroyin abẹle maa n sọ pe “eeyan fi ilu silẹ”, o n ṣiṣẹ fun nnkan bii ọdun mẹwaa pẹlu ileeṣẹ Gabon ni Morocco ati Senegal.

Ologun to fẹran iṣẹ aṣekarakara yii tun farahan ni agbo oṣelu Gabon ni ọdun 2018, nigba to dipoo aburo aarẹ gẹgẹ bii Ọgagun awọn alaabo ilẹ Gabon.

Lẹyin oṣu mẹfa lori ipo yii, Ọgagun Nguema gba igbega si ipo Adari awọn alaabo ilẹ Gabon. O ṣe agbekalẹ awọn eto atunṣe lati rii pe ẹka naa n ṣe daadaa ninu awọn iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ lati maa ṣamojuto ijọba.

Ọgagun Nguema yi oju ewe Gabon pada

Awọn ara Gabon

Oríṣun àwòrán, REX/SHUTTERSTOCK

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eeyan kan to jẹ oṣiṣẹ sọ fun ileeṣẹ French news agency AFP pe Ọgagun naa jẹ “eeyan ti ọpọ fẹran ti kii gbe ohun rẹ soke, to maa n tẹti si gbogbo eniyan to si maa n wa ọgbọn ati wa ni alafia pẹlu eniyan”.

Ko pẹ to bọ sori ipo tuntun rẹ, Ọgagun Nguema ṣe agbekalẹ “akanṣe eto ọwọ mimọ” eyi to wa lati doju kọ awọn ẹsun ikowojẹ.

Ẹwẹ, wọn fi ẹsun kan Ọgagun naa funrarẹ pe o n ko owo ilu pamọ.

Lọdun 2020, iwadii fihan pe ilẹ Amẹrika fi ẹsun kan Ọgagun Nguema ati idile Bongo pe wọn ra awọn dukia olowo nla nla nilẹ Amẹrika pẹlu owo ilu. Wọn ni Ọgagun naa na owo to to miliọnu kan Dollar (£790,000) lori dukia mẹta.

Esi Nguema si eyi ni pe “mo lero pe yala ni France tabi ni Amẹrika, igbe aye ẹni ni igbe aye ẹni, o si yẹ ki wọn bọwọ fun un.

Ẹwẹ, lọtẹ yii, Ọgagun yii sọ fun iwe iroyin Le Monde pe awọn ara Gabon ti ri arito ijọba Ali Bongo to si ni aarẹ naa ko ba ti ma lọ fun saa kẹta.

“Gbogbo eeyan lo n sọrọ nipa rẹ ko si si ẹni to gbọ,”. O ni tori naa ni awọn ologun ṣe pinu lati yi oju ewe naa pada eyi yoo si wọ inu iwe itan Gabon.