Gabon coup: Mọ ohun tó n ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìlànà ráńpẹ́ yìí
Aarẹ Ali Bongo ti wa labẹ isemọle bayii lẹyin ti awọn ologun gbajọba lọwọ rẹ tori abajade eto idibo ti wọn ko fọwọ si.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ologun ni orilẹede Gabon lo ja ijọba gba ti wọn si fo Aarẹ Ali Bongo ẹni ọdun mẹrinlelọgọta si abẹ isemọle.
Igbajọba naa waye laipẹ ti wọn kede esi eto idibo eyi to sọ pe Ọgbẹni Bongo ni wọn tun tun yan pẹlu aduru itako to da lori ẹsun jibiti.
Aarẹ Bongo kọkọ jẹ aarẹ ni ọdun 2009 lẹyin iku baba rẹ, Omar Bongo Ondimba, to ti ṣejọba orilẹede naa fun ọdun mọkanlelogoji.
Gabon ni ilẹ ti o gba ominira kẹyin lọwọ ijọba ilẹ Faranse ti yoo foju ri igbajọba lẹnu ọdun diẹ yii - lẹyin ti Mali, Burkina Faso, Guinea ati eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ni Niger.
Ohun to yẹ koo mọ niyi:
Ki ni idi ti awọn ologun fi gbajọba?
Awọn adari ikọ to gbajọba naa lodi si abajade esi eto idibo, eyi to sọ pe ọgbẹni Bongo lo jawe olubori.
Ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ, ẹgbẹ alatako sọ pe oludije awọn ni oludije to koju osuwọn gangan iyẹn Albert Ondo Ossa to si jawe olubori, bakan naa ni wọn ni ọpọlọpọ eru wa ninu eto idibo naa.
Awọn ologun naa ni awọn ti pinu "lati daabo bo alafia ilu nipa fifi opin si ijọba to wa lori alefa lọwọlọwọ."
Wọn fi kun un pe "Eto idibo naa ko mọnyan lori gẹgẹ bi eto idibo to yanranti to si faye gba ẹtọ ọmọniyan eyi ti awọn ara Gabon n fẹ."
Lẹyin ikede naa, ọgọọrọ eeyan tu si igboro orilẹede Gabon lati fifẹ gba igbajọba awọn ologun naa.
Nibo gan ni Gabon wa?
Orilẹede Gabon kọlẹ si iha Ila Oorun Afirika ti wọn si mọ ọ si ilu to kun fun oniruuru ẹbun Olodumare paapaa epo ati cocoa ṣugbọn o le ni ida mẹta iye eeyan to wa nibẹ to n gbe ninu iṣẹ.
Gabon jẹ orilẹede ti iye eeyan to wa nibẹ fẹrẹ to iye kan naa pẹlu ti ilẹ United Kingdom - eeyan to le ni miliọnu meji (2.4m) amọ ti ida aadọrun orilẹede naa jẹ pe igbo lo bo gbogbo rẹ.

Labẹ iṣejọba Ọgbẹni Bongo, Gabon jẹ orilẹede Afirika akọkọ ti yoo gba owo tori pe wọn din eefin to n tu sita ku nipa didaabo bo igbo wọn.
Ajọ isọkan agbaye, UN fun wọn ni miliọnu mẹtradinlogun dollar eyi to to miliọnu mejila pọun.
Gabon jẹ ilu labẹ ijọba ilẹ Faranse titi di ọdun 1960 to si ti ni aarẹ mẹta pere lati igba naa.Labẹ ijọba aarẹ rẹ keji, Omar Bongo to jẹ baba Ali, ijọba rẹ ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu France labẹ eto kan ti wọn pe ni "Franafrique" lasiko ti Gabon maa n ri iranlọwọ nipa ti oṣelu ati ologun fun pasiparọ idokoowo.
Amọ lasiko ti Ali Bongo nigba to jawe olubori lọdun 2009, gbogbo ibaṣepọ naa lọlẹ ṣuu. Koda ijọba ilẹ gunle iwadii lori iwa jẹgudujẹra ninu idle Bongo bo tilẹ jẹ pe wọn ti dawọ rẹ duro tipẹ.
Ta ni Ali Bongo?
Ali Bongo jẹ eeyan to lọyaya gan - ololufẹ ere bọọlu koda o tun ṣe awo orin funk kan laye 1970s - eyi ti pẹ gan ko to jẹ aarẹ.
Orukọ abisọ rẹ ni Alain Bernard Bongo ni orilẹede alamuleti wọn, Congo-Brazzaville ninu oṣu keji ọdun 1959.
O ṣi wa ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ nigba ti baba rẹ, Omar Bongo gba eku ida ijọba lọdun 1967.
Ni 1973, awọn mejeji yipada si ẹsin Islam eyi lo mu ki orukọ Alain yipada si Ali.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O gba ẹkọ nipa bi a ti n jogun agbara o si ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi minisita fun eto abo ati ọrọ ilẹ okere ko to di aarẹ lẹyin iku baba rẹ.
Lọdun 2018, aisan rọpa rọsẹ kọ lu Ali Bongo eyi to gba sẹgbẹ fun nnkan bii ọdun kan to si yọri si ipe fun ko fi ipo silẹ.
Ṣugbọn o pa wọn ti o si tun dije lasiko eto idibo to ṣẹṣẹ pari yii - ipinu to ṣokunfa rogbodiyan to wa nilẹ bayii.















