Ajá pa ọmọ ìkókó, ṣe ìyá léṣe ní Ìpínlẹ̀ Osun

Aworan Aja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin kan to ṣẹṣẹ bi ọmọ tuntun ti ọpọ mọ si Iya Basira ni awọn meji kan ṣe ikọlu si, ti wọn si yọ ọmọ lẹyin rẹ ni agbegbe Halleluyah, Iso Osun nipinlẹ Osun.

Isẹlẹ ọhun lo waye ni bii ago mẹta ọsan, ti awọn aja meji ọhun si ṣekupa ọmọ ikoko lasiko ti wọn ṣe ikọlu si iya rẹ.

Oṣojumikoro, to ba ileeṣẹ iroyin Abẹle The Punch sọrọ ni bi iya ọmọ ṣe n gbiyanju lati doola ọmọ rẹ ni awọn Aja naa bẹrẹ si ni bu u jẹ, ti a ko si le sọ nnkankan.

"Gbogbo wa kan wo, Awọn ni wọn fo ferese jade kuro ni ile kan ti ko si ẹnikẹni ni ibẹ ti wọn yọ ọmọ lẹyin Obinrin naa."

"Ọmọ yii ko ju ọmọ oṣu marun un lọ. Bi Iya ṣe n ṣe akitiyan lati doola ẹmi ọmọ ni awọn Aja naa n bu u jẹ, ti wọn si ṣekupa ọmọ naa".

"Awọn to ni awọn Aja ni awọn eeyan adugbo mọ, ti a si ti n pe ẹrọ ibanisọrọ wọn ṣugbọn ko lọ. Ẹru ba gbogbo wa ni adugbo, a si ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ Ọlọpaa Estate niluu Osogbo leti."

Agbẹnusọ fun Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fi idi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni ileeṣẹ awọn ti bẹrẹ si ni wa awọn to ni Aja ọhun.

"Ọlọpaa ti gbọ si isẹlẹ yii. A ti bẹrẹ si n wa awọn olowo awọn Aja naa. A o rii pe a fi otitọ mulẹ."