Ó ṣe! Ìyáwó jáde láyé lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo

Aworan Rebecca Oyedotun

Oríṣun àwòrán, Others

Arabinrin Rebecca Oyedotun, to n gbero lati ṣe igbeyawo ni o ṣaadede ṣubu, to si gba ibẹ jade laye lọjọ igbeyawo rẹ niluu Ogbomoso nipinlẹ Oyo.

Iṣẹlẹ abanilọkanjẹ yii lo waye lasiko ti iyawo to ti di oloogbe n ṣe ayẹyẹ ibadọrẹ (bridal shower) pẹlu awọn ọrẹ rẹ.

Baba oloogbe, Pasitọ Oyedotun, ti ile ijọsin C&S ni ọmọ oun ko fi igba kankan ṣe aarẹ, ti awọn ko si ri apẹẹrẹ pe irufẹ isẹlẹ naa yoo waye titi di ago mẹwaa abọ, to ṣaadede ṣubu.

Ko to jade, oloogbe ni o mura lati se igbeyawo pẹlu Abiodun Oluwadamilare lọjọ Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ọdun 2023.

Aworan Rebecca Oyedotun

Oríṣun àwòrán, Others

Aburo ọkọ iyawo ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin abẹle, Nigerian Tribune pe igbaradi ni awọn n ṣe lọwọ lasiko ti iyawo ṣaadede ṣubu.

"Awọn mọlẹbi ọkọ ti pa maalu niluu Ogbomoso, gẹgẹ bi igbeyawo ọmọ kan ṣoṣo ti wọn bi, ti inu ọkọ naa si n dun lai mọ pe iku ti wa ni tosi.

Iya Oloogbe, Ruth Oyedotun, ko le ba awọn akọroyin sọrọ sugbọn Baba oloogbe ni gbogbo erongba awọn ni pe ọmọ awọn yoo pada de lati ile iwosan lati pari ayẹyẹ igbeyawo rẹ.

"Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni a gbe e lọ si ileewosan LAUTECH niluu Ogbomoso. Lẹyin akoko diẹ , o laju, ti a si rii pe o wa laye ṣugbọn ki ilẹ Satide to su ni a rii pe ilera rẹ ko peye, ti a si tun gbe e lọ ileewosan Bowen fun ayẹwo.

"Ọkọ iyawo kan n sunkun ni, ile iwosan ni a wa ni gbogbo ọjọ Satide ."

Baba Iyawo ni alaafia ko de ba ọmọ rẹ, to si jade laye ni owurọ ọjọ Aiku.