Kókó ohun méje tóo ní láti mọ̀ tóo bá ń wá iṣẹ́ tó léè fún ọ ní “visa” ní UK

Asia ilẹ UK

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ijọba ilẹ United Kingdom ti fi ikilọ sita fun awọn to n wa iṣẹ paapaa julọ awọn arinrinajo to n wa ọna ati kuro ni orilẹede wọn lọ si orilẹede miran eyi ti ọpọlọpọ nilẹ Afirika ti n pe ni “japa”.

Eyi jẹ jade ninu ọrọ ti ijọba ilẹ naa fi sita loju opo ayelujara wọn ninu eyi ti wọn ti pese ami meje ti awọn to n wa iṣẹ nilo lati fi sọkan ki ala iṣẹ rere ti wọn ti n la ma lọ di ala buruku fun wọn.

Idi ti ijọba United Kingdom si fi gbe ikilọ yii sita da lori iroyin kan to jade laipẹ yii to n ṣafihan aduru awọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ orilẹede miran ti awọn to mu wọn lọ si UK dede pa wọn ti lẹyin ti wọn ti san owo gọbọi fun abaniwaṣẹ lati le rirnrinajo lọ si UK gẹgẹ bi oṣiṣẹ ti wọn ti ba ri iṣẹ.

Afi ti wọn de UK to di gbọin!!! Ṣaadede ni wọn rii pe otubantẹ lasan, irọ gbaa ni wọn pa fun awọn ti wọn o de ba iṣẹ kankan nibẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, fidio kan gba ori ayelujara kan leyi ti awọn ọmọ Afirika kan paapaa ọmọ Naijiria n pariwo pe awọn to ko awọn lọ si UK ti pa awọn ti. “Wọn ko ri wọn pe lorii foonu wọn bẹẹ si ni wọn ko mọ adirẹsi ile ti wọn n gbe depo depo ti wọn yoo le kan si wọn”.

Wọn n fi igbe yii bẹnu ninu fidio naa ti wọn si tun tu aṣiri pe owo gọbọi ni awọn san fun awọn abaniwaṣẹ ọhun lati rinrinajo lọ si ilu naa.

Ṣe lootọ ni UK ni awọn iṣẹ kan to lee fun eniyan ni “visa”?

Ijọba ilẹ UK ni agbekalẹ awọn ileeṣẹ kan to maa n gba eeyan si iṣẹ ti yoo si tun fun ẹni naa ni iwe irina lọ si ilu naa eyi to maa n fun awọn ara orilẹede mii to ba ku oju osuwọn iṣẹ naa lati maa ṣiṣẹ ni UK.

Ẹwẹ, o ṣe ni laanu wipe iwadi kan ti ileeṣẹ iroyin Sky News ni ilẹ UK gbe jade fihan pe igbesẹ yii ti di ohun ti wọn ba jẹ ti wọn si n lo ni ilokulo to bẹẹ to n ṣe ipalara fun awọn to n wa iṣẹ ti ko ni ifura to fi mọ amọ ọmọ Naijiria.

Tori eyi ni ijọba UK ṣe wa n fa awọn to n wa iṣẹ ni gbogbo ọna leti paapaa awọn ọmọ Naijria lati maa wo awọn ohun ikilọ.

UK

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ohun meje too ni lati mọ too ba n wa iṣẹ ni UK ree

Atẹjade ijọba UK naa sọ bayii wipe: “Awọn nnkan meje yii ni ikilọ fi jade tun awọn to n wa iṣẹ ki wọn ma baa ko sọwọ janduku tabi ko si ewu idanimọ.”

  • Laarin oṣu kinni si oṣu keji ọdun ni wọn maa n woye gẹgẹ bi akoko ti awọn ileeṣẹ to n ba ni wa iṣẹ maa n ṣiṣẹ ju – eyi si maa n pese anfani fun awọn gbajuẹ lati ṣe idan wọn daadaa.”
  • Bakan naa, awọn janduku kan tun n pawọpọ lati ṣe agbejade awọn iroyin to lee tan awọn to n wa iṣẹ lati fi ọrọ ikọkọ nipa ara wọn sita koda to fi mọ owo ara wọn pẹlu erongba pe awọn ti wa lojuna ati ri iṣẹ tuntun.
  • Ipolowo iṣẹ ti wọn ko ba ti kọ bo ṣe yẹ, ti ko ni ẹkunrẹrẹ nipa iye owo oṣu.
  • Ọna ikansiraẹni to mu ifura dani paapaa bi ko ba si nọmba tabi ohunkohun teeyan le fi kan si ẹni lara ipolowo iṣẹ naa ti atẹjiṣẹ email rẹ naa kii ṣe ootọ.
  • Owo oṣu ti ko ṣee gbagbọ - bi owo oṣu to wa lori ipolowo naa ba ju ohun ti ileeṣẹ naa n san gẹgẹ bi ida idaji owo oṣu.
  • Iṣẹ ti ko nilo ifọrọwanilẹnuwo.
  • Ki wọn maa bere owo ti ko tọ. Bi adirẹsi email iṣẹ naa ba n tọka si ibi ti kii ṣe ilẹ UK.

Ẹwẹ, ijọba wa ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ to n fun ni ni iṣẹ pẹlu iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ wa amọ ki awọn eeyan ṣọra paapaa lati awọn orilẹede miran ki wọn ma ṣe bọ sọwọ awọn janduku.