Wo bí obìnrin kan ṣe fi iṣẹ abẹ gba ilé ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀

Ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty

Arabinrin ẹni ọdun mẹrinlolọgbọn ti gba ilé ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ obinrin lati gbe wọ inu ara rẹ fun lílọ.

Nipasẹ iṣẹ abẹ ni wọn fi yọ ile ọmọ náà eyi si n waye fun igba àkọ́kọ́ ni ilẹ̀ United Kingdom.

Awọn Dokita oniṣẹ abẹ ni ilu Oxford lo yọ ile ọmọ naa lẹyin ti ẹ̀gbọ́n arabinrin naa to ti pe ọdun ogoji fi ile ọmọ rẹ ta aburo rẹ lọrẹ.

Àwọn Dokita ni ara awọn ọmọ iya meji yii ti wọn ko fẹ́ ki wọn dárúkọ wọn ti n ya díẹ̀díẹ̀.

Wọn fi kun un wipe aburo ati ọkọ rẹ ti ṣáájú ko ọpọlọpọ ẹyin to n di ọmọ pamọ eleyi ti wọn ti fi oje nnkan ọmọ ọkùnrin pade wọn lati ọjọ yii ti wọn si n duro de asiko ti wọn yoo gbe e sinu ile ọmọ lati dagba.

Ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ Dokita ogún lo pawọpọ ṣe iṣẹ abẹ yii eyi to gba wọn ni bii wakati mẹtalelogun fún iṣẹ abẹ meji eyi to so pọ mọ ara wọn ni ile iwosan Churchill ninu osu keji ọdun yii.

Ẹ̀gbọ́n arabinrin yii ti bi ọmọ meji to si ni oun ko nilo ọmọ mọ. Awọn mejeji n gbe ni England.

Odidi ọdun marunlelogun ni àgbà Dokita to dari awọn to ṣiṣẹ́ abẹ ọhun fi ṣe iwadii nipa ile ọmọ.

Ọjọgbọn Richard Smith sọ fun BBC pé "àṣeyọrí nla" ni iṣẹ abẹ yii.

"Gbogbo rẹ dabii ki eeyan ni imọlara nnkan. O da bii pe gbogbo wa sunkun díẹ̀ nigba taa parí."

Arabinrin to gba ile ọmọ naa kun fun ayọ̀ nla kii ṣe kekere to si n ni ireti pe oun yoo le bímọ - kii ṣe ọmọ kan o, ọmọ meji.

Dokita ni ile ọmọ rẹ to gba n ṣiṣẹ́ daadaa "a si n ṣe amojuto rẹ finifini."

Lẹyin ọ̀sẹ̀ meji ti wọn pari iṣẹ abẹ ni ó obìnrin yii ri nnkan oṣù rẹ.

Bakan naa ni Dokita ni yoo maa lo ogun "immunosuopressive" eyi ti ko ni jẹ ki agọ ara rẹ kọ iṣan to wa lati ara ẹ̀gbọ́n rẹ.

Ewu to wa ninu iṣẹ abẹ ti wọn ṣe yii pọ gan ni ti ilera tori naa wọn yóò yọ ile ọmọ yii lẹyin ọdun meji.

Awọn Dokita

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ta lo lee ṣe iru iṣẹ abẹ gbigba ile ọmọ ẹlòmíràn?

Gẹgẹ bi Dokita ṣe sọ ọ, oniruuru ipenija lo lee sun obìnrin de idi iṣẹ abẹ yii bii ẹni ti ko ni nnkan obinrin fun ibalopọ, ẹni to ti yọ ile ọmọ rẹ àti bẹẹ bẹẹ lọ amọ kii ṣe gbogbo wọn naa lo koju òṣùwọ̀n lati ṣe é.

Awọn oloyun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ewu tó wà nínú gbígba ilé ọmọ ẹlòmíràn

Obinrin to ba fẹ ṣe iṣẹ abẹ ile ọmọ yii gbudọ ronu ewu to maa n bá a rìn gẹgẹ bi iṣẹ abẹ ti wọn n pe ni IVF gan ṣe ni ewu tìrẹ naa.

Bo ba ṣe e tan to bẹ̀rẹ̀ si ni lo ogun "immunosuppressant" naa ko tun ro ewu ogun yìí. Fun àpẹrẹ, ogun naa ni nnkan ṣe pẹlu nini awọn afikun aisan ati ni igba miran, aisan jẹjẹrẹ.

Ibeere mii tun wa ni pe ṣe ogun yii ko lee pa ọmọ to wa ninu lara.

Ẹwẹ, àwọn onímọ̀ nípa iṣẹ abẹ ile ọmọ ni UK ni bi eeyan ba lo ìwọ̀n ogun naa dáadáa, ko ni sewu amọ ṣá, dídán nǹkan wo naa ni gbogbo ìgbésẹ yii.

Ṣé wọn ń ṣe iṣẹ abẹ yìí ní ibòmíràn?

Ninu iwadi, igba àkọ́kọ́ ti iṣẹ abẹ ile ọmọ waye ni ọdun 2000 ni Saudi Arabia.

Awọn tilẹ̀ kọ́kọ́ n kan sara sii gẹgẹ bi àṣeyọrí ni ẹ̀ka eto ilera amọ àṣeyọrí naa ko tọjọ rara. Wọn gbe ile ọmọ naa jade pada nígbà ti ko tii pe oṣù mẹrin gẹgẹ bi awọn iṣan ti wọn gbe wọ inu arabinrin naa bẹ̀rẹ̀ si ni kú.

Ni orílẹ̀èdè Turkey àtàwọn ibo miran naa, wọn ti dán iṣẹ abẹ naa wo amọ lọdun 2014 ni agbaye ri aluyọ nla gẹgẹ bi obìnrin kan ni Sweden ṣe bi ọmọkùnrin pẹlu ilé ọmọ ẹlòmíràn tí wọ́n gbé sinu rẹ.