Quadruplet: Bàbá Ìbẹrin ní òun fẹ́ sálọ àmọ́ òun kò fẹ́ èpè ìyàwó òun ní òun fi dúró

Àkọlé fídíò, Quadruplet: Bàbá Ìbẹrin ní òun fẹ́ sálọ àmọ́ òun kò fẹ́ èpè ìyàwó òun ní òun fi dúró

Yoruba ni ibi ti Erin ti n sunkun aileyin, ni Ajanaku ti n sunkun airi ete bo tiẹ.

Nibi ti awọn idile kan ti n sọkun pe Ọba Oke ko tii da awn lohun lati di ọlọmọ laye, idile kan ree to n sọkun pe ọmọ ti oun bi pọju.

Idile Dauda ati Rukayat Olamilekan to wa nilu Ogbomoso nipinlẹ Oyo, lo wa ninu ironu nla bayii nitori ẹbun ọmọ mẹrin ti Ọlọrun fi da wọn lọla ni ẹẹkan soso.

Saaju ni tọkọtaya naa ti bi ọkunrin kan ati obinrin kan, ki wọn to bi ibẹrin yii, ti wọn jẹ obinrin meji ati ọkunrin meji.

Inú wa kò dùn pé a bí ìbẹrin, a kò tètè rí owó ní kò jẹ́ ká ti ṣẹ́ oyún náà

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori oore kamilaya yii, tọkọ taya naa ni igbe aye le mọ awọn tẹlẹ, ki ọrọ awọn ibẹrin to yii wọ.

"Inu yara kansoso la n gbe pẹlu ọmọ meji, isẹ alapata ni mo n se nigba ti aya mi ko sisẹ kankan.

A ti kọkọ pinnu pe yoo gba wa to ọdun mẹwa ka to le bi ọmọ kẹta amọ lojiji ni oyun de laimọ pe mẹrin lo wa nibẹ.

A ti pinnu pe a fẹ sẹ oyun awọn ibẹrin naa amọ ọda owo lo ja wa kulẹ ti ọjọ fin gori ọjọ, ti oyun si n ga."

Dauda Olamilekan tẹsiwaju pe akoko ti iyawo oun l fun ayẹwo ni jẹbẹtẹ gbe ọmọ le awọn lọwọ pe mẹrin lo ni.

"Meji ni ọmọ ti wọn kọkọ ri lasiko ayẹwo dokita, mo ba bu sẹkun amọ dokita ni ki n sunkun daadaa tori oun tun ri ọmọ meji mii nibi ti wọn sa pamọ si"

Nigba toun naa n sọrọ, iya ibẹrin ni lasiko ayẹwo ni dokita ri ọmọ meji ninu oun eyi to pa oun lẹkun pupọ pe ibo ni owo wa, ti awọn yoo fi tọ wn.

O salaye pe oun si n sọkun lọwọ ni dokita to n se ayẹwo naa ni ki oun yara mura lati sọkun siwaju si nitori oun tun ti ri awọn ọmọ meji miran, nibi ti wn sa pamọ si.

Ibanujẹ nla lo ba wa, ti a ko si mọ oun ti a fẹ se."

Bakan naa ni baba ibẹrin ni oun ti kọkọ salọ amọ oun pada sile iwosan nigba ti oun ro aayan iyawo oun, ti oun ko si fẹ ko sepe fun oun.

Bakan naa ni dokita to se ayẹwo oyun, itọju rẹ ati gbẹbi awọn ọmọ naa sọ iriri wọn.

A 30-year-old butcher in Ogbomoso in Oyo State, Dauda Olamilekan, has described the arrival of the quadruplets delivered by his wife, Rukayat Olamilekan as a blessing that is too much to handle. Olamilekan who made this declaration in an interview with BBC Yoruba explains that his family had earlier been blessed with two children before the quadruplets were born. The husband, Olamilekan of Alfa compound in Ijeru, in Ogbomoso notes that it is only with the help of philanthropists and governments at all levels that the welfare of his new born babies can be guaranteed.