Pínpín ìrẹ̀sì “palliative” bẹ̀rẹ̀ ní Osun

Gomina ipinlẹ Ọsun, Ademola Adeleke ti pàṣẹ fún awọn ìgbìmọ̀ tó wa fun pinpin oúnjẹ iranwọ nipinlẹ Osun láti bẹ̀rẹ̀ pínpín irẹsi ti ìjọba àpapọ̀ fun wọn gẹgẹ bi ohun iranwọ fun awọn eniyan ipinlẹ naa.
Ni ọjọru, ọgbọn ọjọ oṣù Kẹjọ ọdún 2023 ni eto pinpin ounjẹ naa bẹrẹ ni ilu Ede to jẹ ilu kan lara awọn ibi ti ìjọba máa nkò oúnjẹ si.
Kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ Osun, Basiru Salam ṣàlàyé pé ìjọba ìbílẹ̀ mẹwaa ni àwọn yoo ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ si ni pin ounjẹ naa si ki awọn to bọ si awọn ijọba ibilẹ miiran.
Salam ni ìjọba ìbílẹ̀ kọọkan yóò gba àpò Irẹsi 189 ati pe awọn ìjọba ìbílẹ̀ ti awọn ti ma bẹrẹ ni Atakunmosa East, Atakunmosa West, Ayedaade, Ayedire, Boluwaduro, Boripe, Ede North, Ede South, Egbedore àti Ejigbo.



Ẹni tó jẹ́ alaga ijọba ìbílẹ̀ Ayedire, Solomon Akin Ogunbiyi ni pinpin awọn oujẹ naa yoo waye gẹgẹ bí igbimọ to n ri si eto pinpin ounjẹ naa ṣe gbe kalẹ.
Olórí gbogbo Iyaloja nipinlẹ Osun, Mary Oyebode to jẹ ọkan lára àwọn ọmọ ìgbìmò nigba to n sọrọ rọ awọn alaga ijọba ìbílẹ̀ lati ṣe ojuṣe wọn gẹ́gẹ́ bi igbimọ ṣe là a silẹ fún wọn.
Bákan náà ni àwọn dúpẹ́ lọ́wọ́ Gomina Ademola Adeleke fún akoyawo tí wọn ṣe lórí eto pinpin oúnjẹ naa.
Agbenusọ Gómìnà Ademola Adeleke, Mallam Olawale Rasheed náà ṣàlàyé pe o pẹ díẹ̀ kí oúnjẹ iranwọ naa tó dé si ìpínlẹ̀ Ọsun ló mú ètò pínpín náà di àsìkò yìí.
O fi kun pe awọn ṣi n reti ọpọ ounjẹ si laipẹ jọjọ lati ọwọ ijọba apapọ.

















