Factcheck: Ìwádìí BBC fihàn pé lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba ni wọ́n ya àwọn fídíò owó inú àpò tó ń jáde ní Gabon

Lẹyin iwadii tuntun, BBC ti fi idi rẹ mulẹ pe ootọ ni pe lẹyin iditẹgbajọba awọn ologun ni wọn awọn fidio to n jade lati Gabon ninu eyi ti o ṣe afihan awọn oloṣelu kan ni Gabon pẹlu apoti owo.
Meji ninu awọn fidio naa lo ṣe afihan pọ ero ninu ile kan pẹlu apoti ti wọn ṣi silẹ to kun fun owo.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ninu ọkan ninu fidio yii, kamẹra ti wọn fi n ya aworan naa sun si apa ọtun eyi ri fi ọkùnrin kan to wọ aṣọ ro jọ t’awon ọmọ ogun ẹṣọ aarẹ lorilẹede Gabon, ikọ ologun to lewaju iditẹgbajọba to waye ni orilẹede naa lọjọru eyi to yẹ aga mọ aarẹ Ali Bongo ni idi.
Awọn kan n sọ pe ile ọmọ Ali Bongo ni wọn ti ya fidio naa, nigba ti awọn miran n sọ pe ile ibatan rẹ kan ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Fidio miran ti wọn ya fi ọkunrin meji kan han ni ita gbangba pẹlu awọn apoti to kun fun owo lasiko ti wọn fi n fi ọr wa wọn lẹnu wo.
Aworan ọkun ti wọn n fi ọrọ wa lẹnu wo naa ba ti ọmọ Ali Bongo, Noureddin Bongo Valentin, mu nigba ti a fi imọ ẹrọ igbalode yiri rẹ wo.
Noureddin Bongo Valentin ati olori awọn oṣiṣẹ rẹ, Ghislain Ngoulou wa lara awọn ti awọn ologun to ditẹgbajọba fi si ahamọ igbele bayii.
Fact Check: Ṣé òótọ́ làwọn fídíò owó inú àpò tó ń jáde lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní Gabon àbí òfégè?

Oríṣun àwòrán, Screenshot/getty images
Lẹyin ti awọn ologun ditẹgbajọba lorilẹede Gabon awon fidio kan bọ si oju ayelujara eti to n ṣe afihan bi awọn agbofinro ṣe mu oṣiṣẹ ijọba tẹlẹ kan nibẹ pẹlu apo to kun fun obitibiti owo.
Amọṣa BBC ti fi idi rẹ mulẹ pe iroyin ofege wa lara awonfidio naa.
Fidio naa fi bi wọn ṣe mu aarẹ ile aṣofin apapọ orileede Gabon, Guy Nzouba-Ndama lọdun 2022 han.
Ninu fidio yii, Ọgbẹni Nzouba-NDama wa laarin awọn ero lẹyin ọkọ akẹru kan, bi won ṣe n ja kọkọrọ ẹnu apo meji ri wọn si ri to kun fun owo faranse CFA francs
Ẹnubode orilẹede Congo lo ti ṣẹlẹ.
Nzouba-Ndama ni olori ẹgbẹ alatako Démocrates (LD), ki wọn to fi si ahamọ igbele gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ nigba naa.
Awọn to n gbe fidio naa kiri bayi n sọ pe ọgbọ ọjọ oṣu kẹjọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ṣugbọn irọ nla leyi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Oniruuru fidio lawọn eeyan n gbe kiri lori ayelujara ti wọn si n fọnrere pe lati orilẹede Gabon ṣugbọn BBC ko tii fi idi wọn mulẹ gẹgẹ bi ootọ.
Meji ninu wọn fi awọn ọkunrin meji han pẹlu ọpọlọpọ apo ti wọn tu silẹ to si kun fun owo.
Ninu ọkan ninu fidio yii, kamẹra ti wọn fi n ya aworan naa sun si apa ọtun eyi ri fi ọkùnrin kan to wọ aṣọ ro jọ t’awon ọmọ ogun ẹṣọ aarẹ lorilẹede Gabon, ikọ ologun to lewaju iditẹgbajọba to waye ni orilẹede naa lọjọru eyi to yẹ aga mọ aarẹ Ali Bongo ni idi.
Awọn kan n sọ pe ile ọmọ Ali Bongo ni wọn ti ya fidio naa, nigba ti awọn miran n sọ pe ile ibatan rẹ kan ni.
Ọmọ Ali Bongo torukọ rẹ n jẹ Nouredin Bongo Valentin pẹlu oṣiṣẹ rẹ kan, Chislain Ngoulou wa lara awọn ti ijọba ologun nibẹ fi si ahamọ.