Kí ni India ń wá lọ sí inú Oòrùn?

Osu mẹrin ni yoo gba wọn lati de ibudo to n lọ

Oríṣun àwòrán, Isro

Leyin ọsẹ kan to di orilẹede akọkọ ti yoo gunlẹ si itosi gusu oṣupa, orilẹede India tun ti n gbaradi lati lọ sinu oorun.

Ìpinnu wọn ni lati gbe ibudo iwadi ijinlẹ kan lọ sibẹ-eyi ti yoo jẹ akọkọ rẹ - lati le tọpinpin irawọ to sunmọ ọ ju ati lati wadi nípa awọn ohun to n farahan ninu ofurufu ati atẹgun oju ọrun.

Kii ṣe igbesẹ akọkọ niyi lati ṣe iwadii nipa oorun- ibudu iwadi ijinlẹ ofurufu NASA ati European Space Agency (ESA) ti ran ohun imọ ẹrọ sibẹ ṣaaju fun idi kan naa- ṣugbọn ko ni awọn amuyẹ kan.

To ba ri bẹẹ, ki ni Aditya- L1? Eyi lawọn ohun to yẹ ki o mọ nipa irinajo to fẹ rin si ofurufu?

Nigba wo ni Asitya-L1 yoo bẹrẹ irinajo rẹ si ofurufu?

Oju opo ti Aditya-L1 yoo duro si si ibi ti oorun wa.

Oríṣun àwòrán, Isro

Itumọ Aditya lede Sanskrit ati Hindi ni oorun. Bi eto gbogvo ba lọ daadaa, baluu irinna sinu ofurufu naa yoo gbera ni agogo mẹfa owurọ kọja ogun iṣẹju lọjọ Satide ọjọ keji oṣu kẹsan an ni Sriharikota, to wa ni nnkan bii ọgọrun kilomita si ilu Chennai.

Awọn aworan ti ileeṣẹ iwadi ofurufu orilẹede India fi sita se afihan baluu arinrinajo oju ọrun ‘rocket’ ti yoo rin irin naa nibi to duro si ni sẹpẹ ni ibuba ti yoo ti gbera.

Akoko melo ni yoo gba a lati de oorun?

Aworan ojuna ti Aditya-L1 yoo rin

Ibi ti baluu yi n lọ gan jina si aye ni iwọn miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta kilomita (1.5million km).

iwọn perete si ni eyi gan si ibi ti oorun gbe tẹso si, ṣugbọn ilọpo mẹrin aye si oṣupa niyi.

Amọṣa baluu Nasa ti wọn pe orukọ rẹ ni Parker spacecraft pẹlu wa lẹnu irinajo iwadii yii lọwọ, ṣugbọn oun yoo sun mọ oorun ni iwọn miliọnu mẹfa kilomita o le diẹ. Koda bi a se b sọrọ yii o ti kọja Venus. Okan lara awọn aye miran to yi aye ti a wa yi ka.

“Yoo gba Aditya-L1 ni nnkan bii oṣu mẹrin gbako ko to de ibi to n lọ” gẹgẹ bi ileeṣẹ iwadi ofurufu ilẹ India, Indian Space Research Organisation (Isro) ṣe sọ loju opo X , ìyen Twitter tẹlẹ.

Bi ọrọ ba wa ri bayii, ki lo de ti wahala wa pọ to bayii nigba to jẹ pe wọn ko ni sun mọ oorun gangan?

Ki ni afojusun irinajo yii?

aworan iṣẹ Aditya-L1

Oríṣun àwòrán, Isro

Baluu naa yoo se iwadii ayikaa oorunnipa lilo awọn ohun elo iwadi igbalode bii “electromagnetic” ati “particle field detectors.”

Yoo tun sewadii lori ohun to n fa oju ojọ niny ofurufu at’awọn nnkan meremere miran.

Elo lowo ti wọn na lori irinajo iwadi sinu ofurufu yii?

Aworan baluu irinajo naa

Ijọba orilẹede India ya owo to ro miliọnu mẹrindinlaadọta dọla ($46m) sọtọ l’ọdun 2019 fun irinajo iwadii yii.

Ajọ iwadii ofurufu ati oju ọrun lorilẹede India ko tii sorosita lẹkunrẹrẹ lori iye ti wọn na.

Baluu naa ti ṣetan lati gbera

Oríṣun àwòrán, Isro

Lọṣẹ to kọja ni baluu irinajo ofurufu ti ko ni awakọ kankan ba si ori osupa.

Eyi lo india di orilẹede kẹrin, lẹyin Amẹrika, Russia ati China ri yoo balẹ sinu oṣupa.

Orukọ ri wọn pe baluu naa ni Chandrayaan-3 –to tumọ si baluu inu osupa lede Sanskrit