Àwọn olùkọ́ni tó yanṣẹlódì dé báńkì ló bá di gbagaun, ìjọba kò san owó oṣù wọn!

Oríṣun àwòrán, others
Ijọba ti gbe ẹsẹ le owo oṣu awọn olukọni to n yanṣẹlodi lọwọ lorilẹede Ghana.
Ileeṣẹ eto ẹkọ ijọba apapọ lorilẹede naa lo paṣẹ fun ileeṣẹ Oluṣiro owo agba lorilẹede ọhun lati gbegi di owo oṣu kẹjọ awọn olukọ to n yanṣẹlodi naa.
Awọn adari ẹgbẹ olukọ ile ẹkọ ẹkọṣẹ olukọni naa ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti ileeṣẹ eto ijọba apapọ orilẹede ọhun gbe lẹyin ti awọn olukọni naa reti ki owo dun gbagaun ninu aṣuwọn wọn ṣugbọn ti nnkankan ko dun.
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ ile ẹkọ ẹkọṣẹ olukọni lorilẹede Ghana, CETAG Ọmọọba Obeng-Himah ṣalaye fun awọn akọroyin pe, “Nigba ti awọn eeyan wa lọ si ile ifowopamọsi wọn, wn ko ri owo oṣu kẹjọ gba”.
Bawo lọr iyanṣẹlodi naa ṣe bẹrẹ?
Awọn olukọ ile ẹkọ ẹkọṣẹ olukọni lorilẹede Ghana, CETAG gunle iyanṣẹlodi ljọ kini oṣu kẹjọ lori bi ijọba orilẹede naa ṣe kuna lati ṣe amulo ilana iṣẹ tuntun ti wọn fẹnuko le lori lati ọjọ keji oṣu karun un, dun 2023.
Awọn olukọ ile ẹkọ ẹkọṣẹ olukọni lorilẹede Ghana, CETAG ni gbogbo ilana to yẹ lawọn tẹ le ki awọn to bẹrẹ iyanṣẹlodi naa.
Bakan naa ni wọn tun koro oju si minisita feto ẹkọ lorilẹede naa pe o sọ ara rẹ di ajọ oṣiṣẹ ti ofin fun lagbara lati sọ boya iyanṣẹlodi kan tna tabi ko tọna.
Amọṣa awọn alaṣẹ ẹgbẹ olukọni naa ti sọ pe bo wu ijọba orilẹede naa ko ko owo oṣu awọn pamọ, awọn ko ni jami lori jija fun ẹtọ awọn.
Wọn tun fi da awọn ọmọ ẹgbẹ wọn loju pe gbogbo ọna to t labẹ ofin lawọn yoo gba lati ja fun ẹt wọn.















