Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà NARD wọ́gilé Ìyanṣẹ́lódì

Aworan

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library

Ẹgbẹ awọn dokita nilewosan ẹkọṣẹ isegun lorilẹede Naijiria NARD ti wọgile iyansẹlodi ti wọn gunlẹ, ti wọn si ti pada si ẹnu isẹ.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Innocent Orji lo kede ọrọ naa lọjọ Ẹti fun Ileesẹ BBC.

"Ẹ kurọlẹ. A ti wọgile iyansẹlodi, A yoo pada si ẹnu isẹ lowurọ ọjọ Satide ni dede ago mẹjọ."

"A yoo se agbeyẹwo ilọsiwaju naa laarin ọsẹ meji.

O ni ijọba ti pinnu lati san owo ajẹmọnu awọn dokita, ti wọn si ti buwọlu idasilẹ owo iranwọ fun awọn dokita.

Eyi lo waye lẹyin ẹgbẹ NARD wọgile iwọde ti wọn fẹ se kaakiri orilẹede Naijiria lati fi bẹrẹ ẹtọ wọn lọwọ Ijọba.

Gẹgẹ bi Aarẹ ẹgbẹ naa se sọ, nnkan mẹjọ ati sise irọpo awọn dokita to ti kuro lorilẹede Naijiria tabi ti wọn ti jade laye ni awọn n bere fun lọwọ ijọba.

"Iya n jẹ awọn ẹgbẹ wa. Awọn ọmọ Naijiria n jẹ iya pẹlu. Ti ko ba ti si iye dokita to yẹ ko wa ni ile iwosan, ko si bi ko se ni se ijamba fun eto ilera ti a n pe se fun awọn araalu.

"Ko si ẹnikẹni to le sọ fun pe ko si otitọ ninu nikan ti a n sọ."

Orji tun fẹsun kan ijọba bi wọn se kuna lati se ọhun to tọ fun awọn dokita.