Ààrẹ Bazoum yóò kú tí ECOWAS bá fi ogun kọlù wá - Ológun Niger

Oríṣun àwòrán, ORTN
Ikọ aditẹgbajọba ni Niger ti sọ pe awọn yoo ṣeku pa aarẹ Bazoum to wa lakata wọn bi ologun kankan ba fi le kogun jawọn.
Lẹyin wakati diẹ ti ajọ Ecowas ṣepade tan ni Abuja olu ilu Naijiria ti wọn si ni kawọn ọmọ ogun wa ni ṣẹpẹ ni iroyin ikede wọn yi jẹyọ.
Lọjọbọ ni awọn olori orileede Ecowas joko ipade nibi ti wọn ti pinu lati lo ọmọ ogun bi gbogbo ọna ipẹtusaawọ to wa nilẹ ko ba fi ṣiṣẹ mọ.
Aarẹ orileede Ivory Coast,Alassane Outtara sọ lỌjọbọ pe awọn olori ologun to gbajọba ni Niger sọ fun aṣoju America kan pe awọn yoo pa Bazoum ti awọn alamuleti wọn kankan ba kogun ja wọ́n.
Ki lawọn igbiyanju to ti waye saaju
Ileeṣẹ iroyin AP gbe iroyin pe awọn aṣju meji kan ti ko fẹ ki wọn darukọ awọn tun sọ ohun to jọ bẹ pe iku ni yoo ja si lati ọwọ awọn ọmọ ologun to gbajọba ti wọn ba file kogun ja wọn.
Aarẹ Bola Tinubu to jẹ alaga ajọ Ecowas sọ pe gbogbo ọna lawọn yoo lo lati wa ojutu si ọrọ yi ati pe lilo ologun lawọn yoo gbe yẹwọ bo ba doju ẹ tan.
Aarẹ Ivory Coast Alassane Outtara wa lara awọn to loun ko ni bikita lati fi ọmọ ogun ranṣẹ ti Ecowas ba lawọn ṣetan ogun pẹlu Niger.
Irinajo ọrọ pipetu saawọ Niger yi ti jina diẹ.
Lati igba ti ikede awọn ologun ti jade pe awọn gba ijọba lawọn ajọ,orileede ati ọlọdani ti n parọwa alaafia si awọn ologun pe ki wọn da ijọba pada fun aarẹ Mohammed Bazoum.
Ninu awọn to parọwa si wọn lawọn orileede bi France America ati ajọ isọkan agbaye UN.
Nilẹ Africa nibi ajọ Ecowas ati AU naa ko gbẹyin nibi arọwa si awọn ologun yi lati da ijọba pada fun ijọba awarawa ti araalu dibo yan.
Gbogbo ihalẹ Ecowas yi ko wọ ara awọn ologun
Bo ti lẹ jẹ wi pe ajọ to nii ṣe pẹlu ọrọ aje laarin awọn orileede iwọ oorun Africa ni Ecowas jẹ, alaga ajọ naa to jẹ aarẹ Naijiria Bola Tinubu fun awọn ologun o gbajọba ni gbedeke ọsẹ kan lati da ijọba pada.
Gbedeke yii nikan kọ, Ecowas gbe awọn igbesẹ gbigbe igi dina ibode Niger ati awọn igbesẹ to nii ṣe pẹlu ijiya lori akoto owo awọn kan to ni ohun ṣe pẹlu iditẹ-gbajọba yi.
Gbogbo ihalẹ Ecowas yi ko wọ ara awọn ologun titi di ba ṣe n sọrọ yi.
Eleyi lo mu ki ajọ Ecowas wa ni ki ikọ ọmọ ogun awọn orileede ajọ naa wa ni ṣẹpẹ lati kogun ja awọn ologun Niger ti wọn ba kọ lati gbe ijọba silẹ.
Orileede kọọkan ti bẹrẹ si ni jẹjẹ fifi ọmọ ogun ranṣẹ tawọn mii si ni awọn ko ni foju silẹ jẹ ki Ecowas tabi ikọ mii ko ogun ja Niger.
Ninu awọn to lawọn ṣetan lati gbeja Niger ni Mali ati Burkina Faso wa.
Awọn orileede mejeeji yi jẹ eleyi ti o wa labẹ idari ologun.
Se nkan mii wa ti awọn ti ọrọ kan le ṣe lati fi yago fun ogun?
Nibi ọrọ de duro bayii, ko yi ti daju igba ti awọn ikọ ọmọ ogun Ecowas yoo kogun ja Niger.
Ipade Ecowas to waye ṣi tẹnumọ pataki ijiroro dipo kikọju ogun si araẹni lati yanju ọrọ to wa nilẹ yi.
Botilẹ jẹ wi pe ajọ Ecowas sọ pe gbogbo igbiyanju tubi n nubi tawọn gba ni awọn ologun yi tapa si, wọn ko ti fidi igba kan pato ti wọn yoo kogun ja Niger.
Lagbegbe Africa ti Niger wa, ko si ẹni to wu pe ki ọrọ di ogun nitori ipa ti yoo ni lori alaafia wọn.
Ni Naijiria awọn ọmọ Naijiria n parọwa pe ki aarẹ Tinubu wa wọrọkọ fi ṣada ki ọrọ ma dogun nitori ohun to wa lẹyin ọfa o ju eje lọ.
Yala ni agbegbe ariwa Naijiria to ṣe pe wọn sunmọ ibode Niger ni tabi lawọn ipinlẹ mii, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe bukata pọ nilẹ ni Naijiria ju ki aarẹ wa ko awọn ọmọ ogun ti yẹ ko daabo bo ilu lọ jagun Niger.
Ni orileede Niger fun ara rẹ, ọpọ araalu lo jọ pe wọn n ṣe atilẹyin fun ijọba ologun yi.
Idi si ni pe pupọ ri iditẹgbajọba yi gẹgẹ bi ọna ti Niger le fi gba ara rẹ silẹ lọwọ amunisin orileede France.
Kaakiri loju opo ayelujara la ri fọnran fidio ati aworan nibi ti araalu ṣe iwọde atilẹyin fun ijọba ologun ti wọn si lawọn ko faramọ ki araata kogun ja awọn lori ọrọ iṣakoso ilẹ wọn.
Igbesẹ to ku bayii ni ọpọ n reti leleyi ti yoo mu alaafia wa ti ẹmi ko si ni baa lọ.












