Ẹ̀rù ń bà wá lórí ìlera ààrẹ Niger tí ológun yọ nípò, ìrẹsì gbígbẹ ní wọn ń fi tipá fun jẹ - UN

Aworan awọn olufẹhonuhan ni Niger

Oríṣun àwòrán, REUTERS

Akọwe-Agba fun ajọ isọkan orilẹede agbaye, Antonio Guterres, lọjọru fi ero rẹ han lori nnkan to sapejuwe gẹgẹ bi igbe aye to nira pupọ ti Aarẹ Niger ti wọn yọ loye, Muhamed Bazoum ati awọn mọlẹbi rẹ n gbe lakata awọn ologun to ditẹgbajọba.

Agbẹnusọ ajọ ọhun, ninu atẹjade to fi lede ni, Guterres n pe fun itusilẹ Bazoum ati awọn mọlẹbi rẹ ni kiakia.

Eyi waye lẹyin ti iwadi ileesẹ iroyin CNN sọ pe Aarẹ Bazoum nikan lo wa ni ahamọ, ti wọn si fi tipa mu ko jẹ irẹsi gbigbẹ ati awọn ounjẹ miiran ti ko tẹ lọrun ni akata awọn ologun to ditẹgbajọba lọwọ rẹ.

Bazoum fi atẹjisẹ ransẹ si ọrẹ rẹ nibi to ni wọn ko gba oun laye lati ba ẹnikẹni sọrọ lati ọjọ Ẹti, ti wọn ko si fun oun ni ounjẹ ati oogun lati lo.

Aworan awon ologun Niger

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olori ijọba ologun ọhun lo yari kanlẹ lẹyin ọpọlọpọ idunkoko pe ki wọn gbe agbara ijọba pada fun Bazoum.

Saaju ni ọsẹ to kọja, ni ijọba ologun kede olotu ijọba tuntun, Ali Mahamane Lamine Zeine gun ijọba tuntun ti wọn sẹsẹ da silẹ.

Bakan naa ni awọn olorj ologun naa wọgile gbogbo ipe ati ẹbẹ lati ọwọ olori ẹsin lorilẹede Naijiria, Sultan ti Sokoto, Sa'ad Abubakar, Adele Akọwe ijọba fun orilẹede Amẹrika, Victoria ati ọpọlọpọ eeekan eeyan ati ajọ ni ilẹ Adulawọ