Niger Coup: Ìdí márùn-ún tí ìdìtẹ̀ gbàjọba Niger fi kan gbogbo àgbáyé

Awọn alatilẹyin ijọba ologun n fi ayọ han laarin igboro ilu Niamey

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn alatilẹyin ijọba ologun n fi ayọ han laarin igboro ilu Niamey
    • Author, Yusuf Akinpelu
    • Role, BBC News, Lagos

Iditẹgbajọba to waye ni orilẹ-ede Niger ti fa aibalẹ ọkan fun awọn orilẹ-ede to mule ti i, paapaa nipa bi awọn ologun ṣe n gba ijọba ni ẹkun Sahel - ẹkun to bẹrẹ lati Atlantic Ocean titi de Red Sea.

Niger ni orilẹ-ede tuntun tu awọn ologun ti ṣẹṣẹ gbajọba lẹyin ti iru rẹ waye ni Mali ati Burkina Faso laarin ọdun mẹta.

Amọ iyatọ to wa nibẹ ni pe kii sẹ awọn to wa ni ẹkun Sahel nikan ni nnkan to n ṣẹlẹ ni Niger n kọ lomiinu, o ṣeeṣe ko ni ipa jakejado agbaye.

Igbesunmọmi yoo pọ si

Ṣaaju asiko yii, Niger jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede to ṣi n lo ijọba alagbada, ti awọn orilẹ-ede alawọ funfun si n wo o gẹgẹ bi ibi ti alaafia ti jọba ni ẹkun ti awọn ikọlu to lagbara ti n waye.

Amọ ni bayii ti awọn ologun ti gbajọba, ibẹru wa pe o ṣeeṣe ki rogbodiyan tun pọ si i.

Ibudo awọn ọmọ ogun orilẹ-ede France ati America wa ni Niger, nibi ti wọn ti n ṣe iranlọwọ lati gbogun ti Boko Haram ati ISIS. Ọjọ iwaju iranlọwọ naa ko daju mọ̀ bayii. Iditẹgbajọ̀ba to waye ni Mali ati Burkina Faso ti mu ki ikọlu ti awọn agbesunmọmi naa n ṣe tubọ pọ si, eyi lo mu ki ifoya wa pe o Niger naa le di ilẹ ọlọra fun awọn oniṣẹ ibi naa.

Aṣa iditẹgbajọba n moke si i

Iditẹgbajọba to waye ni Niger tumọ si pe gbogbo abala kan ni Africa lo ti wa ni abẹ iṣakoso ologun - lati Mali ni iwọ-oorun titi de Sudan ni ila oorun. Eyi si jẹ irinṣẹ ifasẹyin fun ijọba alagbada ni ẹkun naa.

Iditẹgbajọba to waye ni Niger ṣeeṣe ko fun awọn ileeṣẹ ologun ni awọn orilẹ-ede yooku ni igboya lati ja ijọba gba lọwọ alagbada.

Ibẹru yii jẹ alaye lori igbesẹ ajọ Ecowas, to fi ofin de awọn to ditẹgbajọba naa, to si tun ti dunkooko lati doju ogun kọ wọn, ti wọn ba fi kọ lati da ijọba ijọba pada fun Aarẹ Bazoum. America, ilẹ Europe ati ajọ United Nations lo faramọ igbesẹ yii julọ.

Ọkunrin kan re e to gbe asia Russia dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo tu jade lọ si papa iṣere lati fi atilẹyin wọn han fun ijọba ologun

Agbara Russia yoo gbilẹ si

Lẹyin iditẹgbajọba to waye ni Mali ati Burkina Faso, awọn orilẹ-ede mejeeji bẹrẹ ọrẹ pẹlu Russia. Wọn si ti fi da ijọba ologun ni Niger loju pe, oun naa le tọ ipa ọna kan naa.

Ko si ẹri kankan to fihan pe Russia lọwọ ninu bi ologun ṣe gbajọba ni Niger. Koda, agbẹnusọ ijọba orilẹ-ede naa kan ti pe fun itusilẹ Ọgbẹni Bazoum, ati yiyanju rogbodiyan naa ni ilana alaafia.

Ṣugbọn ṣa, awọn kan to jẹ alatilẹyin ijọba Russia gboriyin fun awọn to ditẹgbajọba lori awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ orilẹ-ede naa ati lori ayelujara Telegram. Bakan naa ni awọn to faramọ iditẹgbajọba naa ta asia orilẹ-ede Russia ni Niger, ti wọn si bu ẹnu ẹtẹ lu France, orilẹ-ede to ko wọn lẹru lọdun pupọ sẹyin.

Ti Niger ba fi ṣe nnkan ti awọn alamuleti rẹ ṣe, nipa fifi ara mọ Russia, paapaa ikọ ologun Wagner Group, eyi le mu ki ikọlu o pọ si, titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ, ati kiko awọn nnkan alumọni lọna aitọ ni Niger.

Ti ohun alumọni Uranium ba bọsi ọwọ awọn ọdaran

Orilẹede Niger lo n pese ida marun un ohun alumọni Uranium ti awọn eniyan n lo lagbaye.

Ohun alumọni yii ni wọn n lo fun ipese ina ọba ti wọn fi ohun ijagun nuclear fi pese. Niger lni orilẹede keji to pọju to n pese ohun alumọni Uranium fun ilẹ Europe.

Bakan naa ni wọn n pese ida marundinlogun Uraninum fun orilẹede Faranse.

Euratom ni nibayii ko si ibẹru nipa asilo ohun alumọni Uranium tabi gbigbe lọ si oke okun ni asiko yii, nitori wọn ṣi ni ipese eleyii ti yoo wa fun lilo fun ọdun mẹta.

Bio tilẹ jẹpe ko si ewu lọwọlọwọ, ajọ Ecowas to fi mọ awọn orilẹede lagbaye ko ni fẹ ki ohun alumọni Uranium ti wọn n lo fun ipese ina fun awọn araalu ati fun ikọ ọmọogun, ko bọ si ọwọ awọn ọdaran tabi awọn ẹni ibi ni agbaye.

Awọn to sẹ ifẹhọnuhan tako ajọ ECOWAS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn to sẹ ifẹhọnuhan tako ajọ ECOWAS

Isọro awọn arinrinajo lọ si oke okun

Aarẹ Bazoum ati ijọba rẹ ki wọn to yọọ kuro ni ipo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn adari lati ilẹ Yuroopu lati ripe o ṣoro fun awọn to fẹ rinrinajo lọ si oke okun lọna ẹburu

Ijọba Bazoum ko fun awọn eniyan lanfaani lati rin irin ajo gba ori agbami Mediterranean, to si buwọlu dida ọgọọrun awọn eniyan pada si atimọle to wa ni Libya.

Bakan naa lo ti gbogun ti awọn oludokowo fifi eniyan ṣe owo ẹru, paapaa lati ilẹ iwọ oorun Afrika ati awọn to wa lati ariwa ilẹ naa.

Amọ nibayii ni ijọba ologun ti gba ijọba yoo lera lati ṣe akoso awọn agbegbe yii nitori orilẹede Faranse ati Ilẹ Gẹẹsi ti kesi awọn adari ijọba ologun nibẹ lati dawọ duro tabi ki wọn foju wina ofin.

Eleyii ni o sẹeṣe ko fa ifaṣẹyin fun fi fi ofin de awọn arinrinajo gba ori agbami mediterranean lọ si ilẹ Yuroopu.