Tí a kò bá fọhùn akin fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìjọba alágbádá ní Niger, kò sí ẹni tí yòó bá wá ṣe é - Tinubu

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @bolatinubu

Alaga ajọ Ecowas, to tun jẹ aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, ti sọ pe afojusun ajọ naa ni lati ri i pe ijọba alagbada fi ẹsẹ mulẹ ni orilẹ-ede Niger.

Tinubu sọ ọrọ yii lasiko to n sọrọ idagbere nibi ipade apero kan to waye niluu Abuja ni Ọjọbọ.

Nibi ipade naa ni Ecowas ti fi ẹnu ko lati pese awọn ọmọ ogun silẹ, ti yoo kọlu awọn ọmọ ogun to ditẹgbajọba ni Niger, lẹyin ti wọn kọ lati tẹle gbedeke ti Ecowas fun wọn lati da ijọba pada fun Aarẹ Mohamed Bazoum.

Aarẹ tinubu sọ pe abajade ipade ijiroro naa fihan jẹ ẹri bi iṣọkan ati ifọwọsowọpọ ṣe lagbara to - to si tun fihan pe Ecowas n ronu nipa awọn eniyan Niger.

“Ijiroro wa fihan pe gbogbo ọna ni a fẹ gba lati da alaafia pada si Niger, to fi mọ lilo ọwọ agbara ati ipa ti gbogbo ọna yooku ba forisanpọn.

“A duro lori ipinnu wa lati ṣe atilẹyin fun Niger ninu irinajo rẹ lati ni eto iṣejọba alagbada to fi ẹsẹ mulẹ. Ti a o ba ṣe e , ko si ẹni to le ba wa ṣe e.”

Tinubu ni lootọ ni ipenija yoo wa, amọ o ni oun ni ireti pe iṣọkan to wa ni ẹkun Iwọ-oorun Africa yoo mu ki awọn bori.

Kókó méjìlá tí ECOWAS fẹnukò lé lórí níbi ìpàdé rẹ̀

Awọn asaaju ECOWAS

Oríṣun àwòrán, ECOWAS

Ni ọjọbọ ni awọn asaaju orilẹede to n se asepọ ọrọ aje lẹkun iwọ oorun Afirika, ECOWAS joko se ipade nilu Abuja.

Aarẹ Bola Tinubu lo gbalejo ipade naa.

Ipade yii si lo waye lẹyin ti gbedeke ọjọ meje ti ajọ ECOWAS fun ikọ ologun to ditẹgbajọba ni orilẹede Niger wa sopin.

Gbedeke naa lo n rọ wọn lati gbe da aarẹ Mohammed Bazoum pada sori aleefa gẹg aarẹ isejọba alagbada sugbọn titi ti gbedeke ọjọ meje naa fi kọja, ikọ ologun ni Niger ko tẹle arwa ajọ ECOWAS.

Lẹyin ipade ọhun, koko ohun ti wọn fẹnuko le lori ni pe ki awọn orilẹede to wa labẹ ajọ ECOWAS naa lọ pese awọn ikọ ologun apẹtusaawọ silẹ lati da ijọba pada fun alagbada.

Amọ yatọ si ipinnu yii, ẹ tun wo koko mejila mii ti ajọ ECOWAS fi ẹnu ko le lori lasiko ipade wọn ọhun.

Koko meje ti ajọ ECOWAS fẹnuko le lori

  • ECOWAS bu ẹnu atẹ lu iditẹgbajọba ọhun ati bi wọn se fi tipa ti aarẹ Mohammed Bazoum mọle pẹlu awọn ẹbi atawọn eeyan to ba se isejọba
  • O tun bu ẹnu atẹ lu ipo ti ko dara ti wọn fi aarẹ naa si ni atimọle, ECOWAS ni ikọ ologun CNSP si ni oun yoo lọ ni asọ mu lori aabo Bazoum ati ẹbi rẹ ti ipalara wa de ba aarẹ naa atawọn ẹbi rẹ
  • ECOWAS tun ni oun duro lori awọn ilana ti wọn fi ẹnu ko le lori nibi ipade wọn to waye ni ọgbọnjọ osu keje ọdun 2023 eyi to da lori iditẹgbajọba ni Niger
  • ECOWAS ni oun si n pinnu pe oun yoo si ilẹkun silẹ fun ijoko jiroro papọ lọna ati yanju aawọ Niger naa pẹlu alaafia
  • O ni oun yoo tun ri daju pe wọn se amusẹ awọn igbesẹ lati ti awọn ẹnu ibode pa, ti ofin ma rinrin ajo to fi de awọn eeyan, ikọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ẹnikọọkan to ba tako aayan alaafia lati da amulo ofin ati isejọba alagbada pada si Niger, yoo si wa si imusẹ pẹlu gbigbe ẹsẹ le awn dukia wọn
  • O tun sekilọ fawọn orilẹede to wa labẹ rẹ, eyi ti iwa wọn taarata tabi ni abẹlẹ n pagidina aayan alaafia lati yanju laasigbo to n waye nilẹ Niger lati ri daju pe amulo ofin pada si orilẹede naa
  • ECOWAS tun kesi ajọ apapọ awọn orilẹede to wa nilẹ Afirika, African Union (AU) lati fi ontẹ lu awọn ipinnu ti wọn fẹnuko le lori lori ọrọ Niger
  • ECOWAS tun kesi awọn orilẹede ati lajọlajọ to jẹ alajọsepọ rẹ, to fi mọ ajọ isọkan orilẹede agbaye, UN lati se atilẹyin fun ECOWAS ninu aayan rẹ lati da amulo ofin pada ni kiakia ati awọn ilana ti wọn fẹ lo nipa rẹ lorilẹede Niger
  • Pasẹ fun aarẹ ajọ ECOWAS lati ri daju pe gbogbo igbesẹ fifi ofin de awọn ologun ni Niger ati awọn alatilẹyin wọn wa si imusẹ
  • ECOWAS tun pasẹ fawọn igbimọ awọn olori eto aabo lawọn orilẹede to wa labẹ rẹ lati pese ikọ ologun silẹti yoo lọ da isejọba alagbada pada sori aleefa ni Niger
  • Ipade naa tun pasẹ pe ki ikọ ologun ti wọn kojọ naa ri daju pe oun se amusẹ amulo iwe ofin pada ni orilẹede Niger
Ipade awọn aarẹ orilẹede Niger

Ecowas fẹ́ fi wèrè wo wèrè ní Niger, Ó ní káwọn ológun gbáradì láti kógun ja àwọn adìtẹ̀gbàjọba níbẹ̀

Ajọ Ecowas ti paṣẹ fun awọn ologun ikọ ologun ajọ naa lati ṣigun kọlu Niger lona ati da ijọba alagbada pada sori oye nibẹ.

Ajọ Ecowas ṣalaye pe niwon bi awọn ọmọogun aditẹgbajọba lorilẹede naa ti ṣe kọ lati jiroro tabi gbọ gbogbo ipẹ ti ajọ naa n ṣe sí wọn lati da aarẹ Bazoum pada sipo, igbesẹ ogun lawọn yoo lo.

Eyi jẹyọ ninu abajade ipade ajọ naa to waye nilu Abuja lori bi ọmọogun aditẹgbajọba ṣe n faake kọri pe awọn ko ni gbe ijọba sílẹ pada fun alagbada.

Ajọ Ecowas paṣẹ fun awọn ọgagun agba ileeṣẹ ologun lawọn orilẹede rẹ lati “bẹrẹ igbesẹ gbigbe ikọ ọmọogun dide pẹlu gbogbo igbesẹ to yẹ ni kiakia.

“ paṣẹ kiko awọn ọmọogun Ecowas lati da iṣejọba alagbada pada ni orilẹede Niger.”

Ajọ naa ṣalaye ninu afẹnuko rẹ naa pe gbogbo onaalaafia to yẹ kati yanju ọrọ pel’awon aditẹgbajọba naa lawọn ti tọ ṣugbọn ti wọn ko fẹ gba.

Bakan naa ni wọn ke s’àwon ajọ orilẹede bii Ajọ ilẹ Afirika AU at’awọn orilẹede agbaye miran lati ti igbesẹ awọn lẹyin

Ko si alaye kikun lori boya aṣẹ yii yoo jasi gbigbe igbesẹ lati ko ogun ja awọn ọmọogun aditẹgbajọba lorilẹede Niger naa ni kiakia tabi boya ki wọn kan si maa gbaradi lasan ni.

Ààrẹ Tinubu ní bó bá kan lílo ọmọogun láti dá ìjọba alágbádá padà sí Niger, Ecowas ṣetán láti lò ó

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, bola tinubu

Aarẹ Bọla Tinubu ti sọ pe ko si ohun tí ajọ Ecowas ko ṣetan lati lo ninu gbogbo awọn ilana to gbe kalẹ lati yanju wahala iditẹgbajọba ni Niger.

Aarẹ Tinubu ni eyi ko yọ lilo ọmọogun silẹ.

O sọrọ yii ninu ọrọ ipari ipade to ka lẹtin ti ipade naa pari nilu Abuja lọjọbọ.

Awọn olori orilẹede labẹ ajọ Ecowas ṣe ipade lẹyin ti gbedeke ti wọn fun awon aditẹgbajọba lorilẹede Niger pari lọjọ Aiku.

Lara awọn aarẹ orilẹede ti wa nibi ipade naa ni:

  • Aarẹ orilẹede Sierra Leone, Julius Maada Bio
  • Aarẹ orilẹede Guinea Bissau, Umaro Mokhtar Sissoco
  • Aarẹ orilẹede Everiste Ndayishimiye
  • Aarẹ orilẹede Ivory coast, Alassane Ouattara
  • Aarẹ orilẹede Mauritania Mohamed Ould Ghazouani
  • Aarẹ orilẹede Ghana Nana Akufo-Addo
  • Aarẹ orilẹede Macky Sall
  • Aarẹ orilẹede Patrice Talon
  • Aarẹ orilẹede Naijiria to tun jẹ alaga ajọ Ecowas Bola Tinubu.

Ẹkunrẹrẹ iroyin yii n bọ laipẹ.