Kò sí àjọṣepọ̀ kankan láàrín àwa àti Asari Dokubo àtàwọn ajaguntà rẹ̀ – Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ pe ko si ajọṣepọ kankan laarin oun ati ajijagbara Niger Delta nigba kan ri, Asari Dokubo, tabi awọn ọmọlẹyin rẹ.
Ṣaaju ni Dokubo ti kọkọ sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu akọrọyin ileeṣẹ iroyin Channels, Seun Okinbaloye, nibi to ti sọ pe oun ni ileeṣẹ ọmọ ogun aladani kan to ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọmọ ogun Naijiria lawọn ipinlẹ kan.
O sọ ninu ifọrọwerọ naa pe “Mi o ni awọn ọmọ ogun o amọ mo ni ileeṣẹ awọn jagunjagun ti ijọba Naijiria bẹ lọwẹ, mo si ti n ṣiṣẹ naa fun ijọba Naijiria.”
“Kaakiri gbogbo agbaye ni wọn ti n ni awọn jagunjagun aladani, a ni awọn ti wọn n pe ni Black Waters, Wagner, ati oriṣiriṣi bẹẹ lo wa.”
“Nitori naa, mo ni awọn jagunjagun aladani ti ijọba n gbeṣe fun, a si n jagun ni fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun ijọba.”
“Lara awọn ibi ti a wa ni Niger, Plateau, Abia, Imo ati apakan ipinlẹ Rivers, a tun wa ni Anambra pẹlu.”
“Iṣẹ takuntakun la n ṣe, awọn eeyan ilu ti a ti n ṣiṣẹ si n gboriyin fun wa.”
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti ni oun ko ṣiṣẹ kan ri pẹlu awọn ọmọ ogun Asari Dokubo.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, Brig.Gen. Onyema Nwachukwu, lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch.
Punch jabọ pe Nwachukwu ni ileeṣẹ naa ko ni ajọṣepọ kankan pẹlu Dokubo tabi awọn ajagunta rẹ.
Nwachukwu ni “A fẹ ko wa ni akọsilẹ lodi si awọn nnkan to sọ, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ko tii ṣiṣẹ kankan ri, ni ajọṣepọ tabi ni kẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Asari tabi ileeṣẹ ologun to n ṣoju fun lawọn agbegbe to darukọ tabi awọn agbegbe mii ti a ti ṣiṣẹ de.”
Ìdí nìyíí tí sójà 25 fí kọ ìwé fí iṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo - Iléeṣẹ́ ológun

Oríṣun àwòrán, Others
Ikọ ọmọogun orilẹede Naijiria ti sọrọ soke lori ọmọogun marundinlọgbọn to kọ iwe fi ipo silẹ.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọmọogun Naijiria fi lede, ni wọn ti ni awọn ọmọogun naa fi iṣẹ silẹ lati inu ọkan wọn ni, kii ṣe pe eniyan kan kan an ni ipa fun wọn.
Ileeṣẹ ọmọogun ni ikọ awọn mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ, to si ni awọn ofin to de bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ wọn.
Agbẹnusọ fun ikọ ọmọogun Naijiria, Ọgagun Onyama Nwachukwu lo fi lede bẹẹ fun awọn oniroyin ni ilu Abuja.
Nwachukwu ni awọn ọmọogun naa gba lati fẹyinti fun ara wọn, to si bu ẹnu atẹ lu iroyin ẹlẹjẹ to ni pe magomago ni ileeṣẹ ọmọogun lo wa ni idi bi awọn ọmọogun naa ṣe kọ iwe fi iṣẹ silẹ.
Amọ ikọ ọmọogun ni iroyin naa fẹ mu ki awọn ọmọogun ni irẹwẹsi ọkan ni, paapaa awọn to wa ni oju ogun, ti wọn si n sa ipa wọn lati da abo bo ilu.

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn oniroyin ofege naa fẹ da aigbọraẹniye silẹ laarin awọn ikọ ọmọogun naa.
Amọ ileeṣẹ ọmọogun naa ni gbogbo awọn oniroyin ofege naa ti ọwọ wọn ba ba ni yoo fi oju wina ofin.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọogun naa ni awọn kii ṣe iṣẹkiṣẹ nitori awọn mọ ẹtọ awọn, ti awọn si mọ iṣẹ wọn lati ṣe ni ọna to tọ ni abẹ ofin.
Ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria fikun un pe ofin gba awọn oṣiṣẹ laaye lati fẹyinti nigba ti o ba wu wọn, lai si ẹni to lee da wọn duro.
‘’Gbogbo igba ni an ṣiṣẹ lati ṣe atilẹyin fun awọn oṣiṣẹ wa lai ṣi pe a yan wọn jẹ.
‘’Ti wọn ba ti tẹle ofin to rọmọ fifi iṣẹ silẹ, ko si ẹni to lee da wọn durọ.
‘’Nitori naa ko si otitọ ninu iroyin pe niṣe ni wọn ni ki wọn lọ rọku nile.’’
Bakan naa ni a n pese eto iwosan fun wọn to fi mọ, eto ile gbigbe, ti wọn tilẹ ni anfaani lati lọ si oke okun fun iwọsan to peye.















