Ìjàmbá iná mú ẹ̀mí 53 lọ, èèyàn 1000 di àwátì

O kere tan, eeyan mẹtalelaadọta lo ti jade laye bayii nitori ina nla kan to n jo ni Hawaii.
Bakan naa, o ti to ẹgbẹrun kan eeyan ti wọn n wa ni erekusu Maui, ti ina ọhun ti sẹyọ, eyi to tii buru julọ ni orilẹede Amẹrika.
Ina ọhun to bẹrẹ si n jo lati ọjọ Iṣẹgun ni wọn ko tii ri pa titi ti di asiko ti a n kọ iroyin yii, eyii to mu ki ọpọ awọn to wa lagbegbe ina naa sa asala fun ẹmi wọn nipa bibẹ sinu odo.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi sọ ninu atẹjade kan pe nnkan bii ẹgbẹrun marundinlọgbọn eeyan lo n wa ni erekusu Maui ti ina ọhun ti bẹrẹ, eyii to ṣakoba fun ọpọlọpọ ile ati awọn ileeṣẹ loriṣiriṣi.
Ko din ni ẹgbẹrun meji ékà ilẹ ti ina ọhun ti gba bayii.

Oríṣun àwòrán, reuters
Aṣoju erekusu Maui ti ina naa ti ṣẹyọ sọ ninu atẹjade kan pe “Lati igba ti ina naa ti bẹrẹ ni a ko tii sinmi ninu igbiyanju wa lati rẹyin rẹ, lọwọ yii, eeyan mẹrindinlogoji lo ti jade laye.”
Ẹwẹ ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ilẹ Amẹrika, US Coast Guard, ti doola eeyan mejila ti wọn kan lu omi latari iṣẹlẹ ọhun.
Gomina ilu ti ina ọhun ti bẹrẹ, Josh Green sọ pe “Pupọ ninu ilẹ Maui lo ti jo gurugu bayii nigba ti ọpọ awọn eeyan ilu ọhun ti di alainilelori.
Iroyin ni nnkan bii ẹgbẹrun mejila eeyan, ti ọpọ wọn jẹ arinrinajo afẹ, lo n gbe ibẹ.
Awọn fidio ti awọn ti ina ọhun ṣoju wọn fi sori ayelujara ṣafihan bo ṣe lagbara to ati bi awọn eeyan ṣe n kan lu omi ki wọn le sa asala fun ẹmi wọn.
Ijọba Amẹrika ti fi ọkọ ofurufu ‘helicopter’ mẹta ranṣẹ lati ran Hawai lọwọ.
Bẹẹ naa ni ọkọ oforufu ileeṣẹ ọmọ ogun n da omi ti iye rẹ le ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ galọnu lati ofurufu silẹ.
Yatọ si awọn ile ati dukia to ṣofo, ọpọ arinrinajo afẹ lo ha si agbegbe ibi ti ina naa ti n jo amọ ijọba ti sọ pe iṣẹ n lọ lọwọ lati doola wọn.














