Iná ṣẹ́yọ nílé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ń ṣe ọlidé, èèyàn mẹ́sàn án jáde láyé

France

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ti ri oku eeyan mẹsan an yọ nigba ti awọn meji mii wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun lẹyin ina to ṣẹyọ nile kan ni France.

Iroyin ni ile ti iṣẹlẹ naa ti waye jẹ eyii ti awọn to ṣoro fun lati kẹkọọ n lọ gẹgẹ bii ibi tiwọn ti n lo isinmi lẹyin saa ẹkọ.

O to ọgọrin oṣiṣẹ panapana to lọ si La Forge lati pa ina ọhun lẹyin ipe pajawiri kan si ọofisi ajọ naa ni nnkan bii aago mẹfa iidaji.

Ijọba agbegbe naa ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn to di awati nibẹ ti ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Bo tilẹ pe jẹ wọn ti pana ọhun bayii, ko si ẹni to tii le sọ ohun to ṣokunfa rẹ.

"Eeyan mẹtadinlogun ni wọn ti ri yọ kuro ninu ile naa nigba ti ẹnikan ti dero ile iwosan"

Eeyan mẹtadinlogun ni wọn ti ri yọ kuro ninu ile naa nigba ti ẹnikan ti dero ile iwosan.

Adari awọn adoola ẹmi to n ṣiṣẹ nibẹ sọ pe awọn ti n wa awọn meji to di awati.

Philippe Hauwiller sọ pe o ṣoro fun awọn lati ṣawari awọn eeyan naa latari awọn orule to wo sibẹ.

O ni “orule atawọn nnkan mii to dawo sibẹ ko mu ko rọrun fun wa lati lọ si aja keji lati wa awọn to ku.”

Agbegbe Wintzenheim ni iṣẹlẹ naa ti waye, ni eyi to jẹ ala ilẹ Germany ati aadọrin kilomita siluu Strasburg.

Olootu ijọba France, Élisabeth Borne ati minisita fun ọrọ idile, Aurore Bergé ti sọpe awọn yoo lọ si Wintzenheim lati ba wọn ti ọrọ naa kan kẹdun.

Ẹwẹ, minisita ọrọ abẹle, Gérald Darmanin, ti kan sara si awọn oṣiṣẹ panapana fun akitiyan wọn lati pa ina ọhun ati lati doola awọn ti ori ko yọ nibẹ.