Ọkùnrin kan fìpá ba ọmọ ọdún mọkànlá lòpọ̀ ní balùwẹ̀, àṣírí tú

Aworan Afurasi

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni ọwọ ti tẹ ọkunrin kan ẹni Ogun ọdun, Hammed Lawal fun ẹsun pe o fi tipa ba ọmọdebinrin, ọmọ mọkanla sun ninu baluwẹ ni agbegbe Aiyepe Ijebu ni ijọba ibilẹ Odogbolu nipinlẹ Ogun.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa Omolola Odutola lo kede ọrọ naa ninu atẹjade to ransẹ si awọn akọroyin ni Ọjọbọ.

Gẹgẹ bi o sẹ sọ, awọn obi ọmọ naa lo wa fi ẹjọ sun pe ọkunrin kan fi pa ba ọmọ wọnbinrin lopọ ninu baluwẹ rẹ.

"Baba ọmọ naa salaye pe fun ọjọ pipẹ ni afurasi naa ti n fi lọkulọ lọ ọmọ oun sugbọn ko sọ igbesẹ to gbe lati le afurasi kuro lọdọ ọmọ rẹ.

"Ọmọ naa lo ti wa ni ile wosan General Ogbogbolu fun ayẹwo ati ibanisẹorọ.

"Ofin ilẹ Naijria ko fi aye igba fipabanilọpọ paapa fun awọn ọmọde to wa ni ọdun mẹtala, ẹwọn gbere ni ijiya ẹsun yii.

"Pẹlu ofin Afurasi naa lo ti kọja Ogun ọdun, ti yoo si foju ba ileẹjọ laipẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti gba ipe fun igba mẹrin ọtọọtọ lọsẹ yii lori ifipanilopọ.

O fikun pe Kọmisọna fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Abiodun Alamutu n rọ gbogbo obi ati alagbatọ lati se amojuto awọn ọmọ lọwọ awọn ọdaran yii.

Àkọlé fídíò, Quadruplet: Bàbá Ìbẹrin ní òun fẹ́ sálọ àmọ́ òun kò fẹ́ èpè ìyàwó òun ní òun fi dúró

Ọkùnrin mẹ́rin wọ gàù torí wọ́n fipá bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀

Ile ẹjọ majistreti kan niluu Owere, nipinlẹ Imo ti ni ki awọn ọkunrin mẹrin kan lọ maa mu gari lọgba ẹwọn fun igba diẹ.

Aṣẹ yii ko ṣẹyin ẹsun pe wọn fi ipa ba ọmọ ọdun marundinlogun kan lopọ, lagbegbe Amarika, niluu Owere.

Ile ẹjọ naa ni awọn afurasi ṣẹ ẹṣẹ ọhun laarin oṣu kọkanla, ọdun 2022, si oṣu Kẹta, ọdun 2023, eyii to lodi si ofin iwa ọdaran orilẹ-ede Naijiria, abala 357.”

IMO STATE POLICE COMMAND

Oríṣun àwòrán, IMO STATE POLICE COMMAND

Lara ẹsun naa ka pe “Ẹ lo agidi ati idunkokomọni pẹlu rẹ, ẹ si tun sọ pe ẹ o ṣekupa a ti o ba sọrọ naa fun ẹnikẹni.”

Iwe ẹsun ọhun sọ siwaju si pe awọn afurasi naa ṣe ọmọdebirin ọhun ni iṣekuṣe to bẹẹ ti aye rẹ ko ni wa bakan naa mọ.

Ṣaaju ni adajọ ile ẹjọ majistreti naa ti kọkọ sọ pe oun ko ni gba ẹjọ naa nitori ile ẹjọ ọhun ko lagbara lati gbọ irufẹ bẹẹ.

Amọ lẹyin ti agbẹjọro to gbe ẹjọ naa wa sọ pe ọmọ ọhun ko gbadun mọ, ati pe o ṣeeṣe ko jade laye, adajọ naa gba lati ṣe ẹjọ ọhun.

Adajọ naa wa kọ lati gba beeli awọn afurasi, o si pasẹ ki wọn wa lọgba ẹwọn ilu Owere titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.

Lẹyin naa lo fa ẹjọ ọhun le ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Imo to n ri si irufẹ ẹjọ bẹẹ lọwọ.