Kí gan-an ló pa Pasitọ Taiwo Odukoya?

Oríṣun àwòrán, Pastor Taiwo Odukoya/instagram
Ọpọ eeyan ni agbo awọn ọmọlẹyin Kristi ati awọn mii lo ti n ṣe idaro pasitọ agba ijọ Fountain of Life Church, Taiwo Daniel Odukoya, to jade laye.
Alẹ ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade sita pe Pasitọ Odukoya kú si America, lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
Lati igba ti iroyin iku rẹ ti jade si ni awọn eeyan ti beere pe ki gan-an lo ṣe iku pa ojiṣẹ Ọlọrun naa.
Botilẹ jẹ pe ẹbi tabi ile ijọsin rẹ ko tii sọ ohunkohun to fa iku rẹ, nnkan ti ọpọ eeyan n sọ lori ayelujara ni pe o le jẹ ibanujẹ ọkan lo sẹ okunfa iku Pasitọ Odukoya.
Eyi ni wọn ni ko ṣẹyin awọn ibanujẹ ati ọfọ ti oloogbe naa la kọja sẹyin ṣaaju iku rẹ.
Lara nnkan ti wọn n tọka si ni iku iyawo rẹ akọkọ, Pasitọ Bimbo Odukoya, to ku ninu ijamba baalu Sosoliso to waye niluu Port Harcourt, lọdun 2005.
A le sọ pe pataki ni Bimbo jẹ ninu igbe aye Pasitọ Odukoya, nitori pe wọn jọ n ṣe iṣẹ iranṣẹ ni, ti Bimbo paapaa si gbajumọ pupọ gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun.
"Ọsẹ kan lẹyin ti iyawo keji rẹ ku, ni Kehinde rẹ naa fi aye silẹ"
Ọdun 2010 ni Pasitọ Taiwo Odukoya fẹ iyawo miran lẹyin ọdun marun-un ti iyawo rẹ akọkọ ku.
Amọ iku tun doro, pẹlu bi iyawo keji ọhun, Nomthi, ọmọ orilẹ-ede South Africa naa tun ṣe dagbere faye lọdun 2021, lẹni ọdun mẹtadinlaadọta.
Aarun jẹjẹrẹ to pa Nomthi, to bi ọmọ meji fun pasitọ naa.
A fi bi ẹni pe ibanujẹ iku iyawo rẹ ko to o ro, ọsẹ diẹ lẹyin naa ni Kehinde rẹ naa tun jade laye.
Awọn nnkan yii ni ọpọ n ro pe o fa ọgbẹ ọkan fun oloogbe, Pasitọ Taiwo Odukoya.
Ọpọ gbagbọ pe ẹni ija o ba lo n pe ara rẹ ni ọkunrin, ati pe ọgbẹ ọkan yara pani ju aisan lọ, paapaa to ba nii ṣe pẹlu iku ololufẹ tabi ẹni to sun mọ eeyan.
Awọn iroyin kan ti a ko le fidi wọn mulẹ ti ẹ n sọ pe lati igba ti iyawo rẹ keji ati Kehinde rẹ ti ku lọdun meji sẹyin, ni oloogbe ti n ṣe aisan wẹrẹwẹrẹ, to kan n fi ọkan akin ati itunu Ẹmi-Mimo ṣe ara giri.
Awọn kan ti ẹ sọ pe itọju aisan lo lọ fun ni orilẹ-ede America, nibi ti ọlọjọ ti de ba a.
Sanwo-Olu, Tope Alabi ati awọn gbajumọ n ṣe idaro
Ọpọ eeyan lo ti n sẹ idaro pẹlu ẹbi ati awọn ọmọ ijọ Fountain of Life Church, ti Pasitọ Taiwo Odukoya da silẹ.
Lara awọn eeyan to ti ranṣẹ ibanikẹdun ni gbajumọ akọrin ẹmi, Tope Alabi.
Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Alabi sọ pe akọni ninu igbagbọ naa ti lọ sinmi ni.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu naa ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ọrẹ timọtimọ ati arakunrin oun.
O ni iroyin iku rẹ jẹ airotẹlẹ.
"Olufkansin tootọ ni, ti igbagbọ ati igbẹkẹle rẹ ninu Ọlọrun ko yẹ rara, lai fi gbogbo ipenija to la kọja ṣe."
Bakan naa ni Sanwo-Olu ba awọn ọmọ ti oloogbe fi silẹ, Tolu Ijogun, Jimmy Odukoya, Tobi Enuha, Jomiloju ati Timilehin Odukoya, to fi mọ ijọ rẹ, ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi, CAN, ati PFN,kẹdun.
Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, Taiwo Odukoya jáde láyé

Oríṣun àwòrán, pastortaiwo
Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe oludasilẹ ijọ Fountain of Life Church, pasitọ Taiwo Odukoya ti jade laye.
Awọn alaṣẹ ijọ ọhun lo fi ikede ipapoda rẹ lede loju opo Facebook ijọ naa.
Iroyin sọ pe ana, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 ni oluṣọagutan naa fu aye silẹ.
Atẹjade naa ni “Awa ọmọ ijọ Fountain of Life Church, ni gbigba amuwa Ọlọrun kede iku baba wa, olukọ ati iranṣẹ Ọlọrun alaaye Daniel Taiwo Odukoya to jade laye lọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 nilẹ Amẹrika.
“A ti gba fun yin Ọlọrun.”
“Adupẹ fun igbe aye rere ti adari wa gbe loke eepẹ.”

Oríṣun àwòrán, pastortaiwo
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Ta ni Daniel Taiwo Odukoya?
Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 1956 ni wọn bi Taiwo Odukoya niluu Kaduna, nibi ti wọn ti tọ ọ dagba.
Oun ni oluṣọagutan agba ijọ Fountain of Life Church to wa ni Ilupeju niluu Eko, ti iye awọn ọmọ ijọ rẹ si le ni ẹgbẹrun mẹjọ.
Ọdun 1980 ni ologbe naa pade iyawo rẹ, Bimbo Williams, ti wọn si ṣe igbeyawo lọdun 1984.
Lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2005, Bimbo Odukoya ku sinu ijamba ọkọ ofurufu Sosoliso to ja lulẹ pẹlu ọgọrun le meji eeyan mii.
Lọdun 2010, Taiwo Odukoya fẹ iyawo miran, Rosemary Simangele Zulu, to jẹ ọmọ orilẹ-ede South Africa.
Amọ nigba ti yoo fi di oṣu Kọkanla, ọdun 2021, o padanu iyawo rẹ keji ọhun sọwọ arun jẹjẹrẹ.













