Ìdùnù subú lu ayọ̀ fáwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ bí Ilé aṣòfin Oyo ṣe gbà àbá ìkéde August 20 bii ọjọ́ ìsinmi fọ́dún ìṣẹ̀ṣe

Awọn onisẹse

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti fọwọsi abadofin to n pe fun yiya ọjọ kan silẹ fun awọn olujosin ẹṣin abalaye nipinle naa.

Ijoko ile igbimọ aṣofin ọhun lo waye lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo ti pada ṣẹnu iṣẹ lẹyin iyanselodi ọṣẹ kan ti wọn gunle,ti Adebo Ogundoyin to jẹ abenugan ile igbimọ ṣe olori rẹ.

Nigbati o n gbe aba naa kalẹ, olori ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ nilẹ igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, ti o tun n ṣoju ijọba ibilẹ guusu Ogbomoso, Sanjo Adedoyin ninu aba naa ṣalaye pataki gbigbe aṣa ilẹ Yoruba larugẹ.

Sanjo Adedoyin, Onigbọwọ aba naa, wa tẹnumọ pe o to akoko ti ipinle Oyo naa yoo fi aye gba awọn ẹlẹsin abalaye lati ṣe ayẹyẹ wọn, papaajulọ pẹlu bi ẹṣin Kristẹni ati Mùsùlùmí ṣe ni ọjọ to so mọ ayajọ ọjọ awọn oludasilẹ wọn.

Aworan ile igbimọ ipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Oyo Assembly

Ọmọ ẹgbẹ ti o n ṣoju ijọba ibilẹ Atiba nilẹ igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ṣalaye wipe gbigbe Ọjọ Iṣẹṣe kalẹ nipinlẹ Oyo yoo mu idagbasoke ba ede Yoruba laarin awọn ọdọ ipinlẹ Oyo ti yoo si tun mu idagbasoke baa ọrọ ajẹ ipinlẹ Oyo.

Nigbati to n fara mọ abajade ijiroro ile igbimọ aṣofin, Adebo Ogundoyin fi onte lu yiyan ogunjọ oṣù kẹjọ gẹgẹ bi ọjọ ti wọn yan sọtọ lati ṣe ayajọ ọjọ iṣẹṣẹ nipinlẹ Oyo.

Pẹlu bii ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti gba aba naa, o seṣee ki Gomina Seyi Makinde fọwọsi aba ọhun kosi di ofin laipẹ ọjọ.

"Lasiko ti a n polongo ibo ni Gomina ti jẹ ko di mimọ fun awọn onisẹse pe oun yoo gbọ ipe wọn, to si ni ki awọn ba ile gbimọ asofin sọrọ."

Awọn aṣofin to gbe abadofin naa wa si ile asofin ni Sanjo Onalapo lati Guusu Ogbomoso, Gbenga Oyekola lati Atiba ati Gabriel Akinjide lati ariwa ibandan.

Adari ile Rt Hon Debo Ogundoyin wa kede pe ile igbimọ aṣofin ti tẹwọgba abadofin naa, ti isẹ yoo si bẹrẹ le lori.