Wo ohun tí Toyin Adegbola àtàwọn ẹbí sọ níbi ètò ìsìnkú Iyabo Oko

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Toyin Adegbola, ti ṣalaye eredi ti ọpọ ero ko fi yọju sibi eto isinku ọkanla lara wọn, Iyabo Oko to di oloogbe.
Adegbola ni awọn ko kede eto isinku naa ni ko jẹ ki ọpọ ero yọju.
Toyin lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba ni iboji ti wọn sin oloogbe ọhun si.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọrẹ tipẹtipẹ ni oun ati oloogbe naa, koda lati kekere ni wọn ti n ba ara wọn bọ.
O ni “To ba jẹ pe ṣe ni a kede fun gbogbo aye nipa eto isinkun yii, ibi ti a wa yii ko ni gba ẹsẹ, gbogbo aye lo mọ bẹẹ, ṣugbọn a sọ pe a fẹ ko jẹ laarin awọn mọlẹbi nikan.”
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Nipa awọn ohun manigbagbe ti Toyin yoo maa ranti nipa oloogbe naa, o ni kii ṣe onijọgbọn, ko si fẹran ija rara.
O ni “Ara rẹ naa ni mo ti kọkọ sọ yẹn pe Iyabo kii fẹ ka ja... O maa ri daju pe ija naa pari, ekeji ni pe Iyabo kii ṣe ki ẹni ma ni.”
Lẹyin naa lo gbadura fun awọn ọmọ oloogbe pe Ọlọrun yoo tọju awọn naa, o si gba aṣaaju wọn nimọran pe ko ko awọ aburo rẹ mọra, ko si ṣe bi iya fun wọn.
Ọkan lara awọn ọmọ Iyabo Oko, Aishat Adebsi Odukanmi sọ fun BBC Yoruba pe ọrẹ timọtimọ loun ati iya oun, oun ko si ni gbagbe rẹ lailai.
Pẹlu omije loju ni Aishat fi daro iye rẹ naa to di oloogbe.
Lara awọn oṣere tiata Yoruba to wa nibi eto isinku naa ni Aderupoko, Tamotiye, Ayobami Olabiyi, to ṣoju Mr Latin to jẹ Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Òṣèré tíátà ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Iyabo Oko bó ṣe ń wọ káà ilẹ̀ sùn

Oríṣun àwòrán, IYABO OKO/INSTAGRAM
Ọpọlọpọ gbajugbaja oṣere tiata lo ti balẹ si ilu Ile Ife lati se ayẹyẹ ikẹyin fun gbajumọ oṣere tiata, Kudirat Odukanmi, ti ọpọ mọ si Iyabo Oko.
Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2023 ni Iyabo Oko jade laye lẹyin to wa ni idubulẹ aisan fun ọjọ pipọ
Toyin Adegbola ti ọpọ mọ si Toyin Asewo to re Mecca lo gbe aworan bi apapọ ẹgbẹ oṣere tiata se bu ọla ikẹyin fun oṣere naa niluu Ile Ife.
Lara awọn nnkan ti wọn se ni bi ayẹyẹ eto isinku agba oṣere naa ni Orin kikọ Ere oritage ati akojọpọ awọn oṣere lati kọrin ikẹyin fun ẹni wọn to jade laye.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ninu oṣu Kinni, ọdun 2022, ni iroyin iku oṣere naa kọkọ jade, ṣugbọn awọn ọmọ rẹ tun pada kede lẹyin wakati diẹ pe iya awọn ko ku mọ.
Awọn ọmọ rẹ sọ fun BBC nigba naa pe lẹyin wakati mẹta ti iya awọn ti gbẹmi mi, lo tun pada si aye.
Ninu oṣu Kẹta ọdun 2022, ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja oṣere tiata naa wa sọ fun BBC Yoruba pe agba oṣere naa ti n gbadun, bo tilẹ jẹ pe o ku ni ibọn n ro.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ta ni Iyabo Oko?
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1960 ni wọn bi Iyabo Oko, niluu Iwo nipinlẹ Osun, gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa lori ayelujara Wikipedia.
Ni 1973 si lo bẹrẹ iṣẹ ere ori itage nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹtala, labẹ ẹgbẹ oṣere Eda Onile Ola.
Oloogbe Kudirat Odukanmi bẹrẹ si ni di ilumọọka oṣere lẹyin to kopa ninu fiimu Oko, ti Adebayo Salami 'Oga Bello' kọ.















