Wo kókó pàtàkì nípa sáà bọ́ọ̀lù Premier League tuntun tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Opin ọsẹ ti a wa yii ni saa bọọlu Premier League tuntun yoo bẹrẹ.
Saa to kọja ni Manchester City gba ife ẹyẹ idije naa fun igba kẹta lera lera lẹyin to din dundu iya fun Arsenal ni aṣekagba rẹ.
Ni idakeji, ẹgbẹ agbabọọlu Southampton, Leicester ati Leeds ja kuro patapata ninu idije naa nigba ti Burnley, Sheffield United ati Luton Town gba ipo wọn.
Ni bayii, gbogbo ẹgbẹ agbabọolu ti yoo kopa ninu idije naa lo ti ṣetan lati bọ sori papa ninu igbiyanju wọn lati gba ife ẹyẹ naa lọwọ Manchester City to wa.
Opin ọṣẹ to jẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ ni idije naa yoo gberasọ ni pẹrẹwu.
Saa tuntun yii ni Manchester City yoo tun gbiyanju lati gba ami ẹyẹ idije naa fun igba kẹrin leralera.
Saa bọọlu ọdun 2023 yii n fi ọsẹ kan le si akoko to bẹrẹ ni saa bọọlu 2022/2023, eyii ko ṣẹyin idije ifẹ ẹyẹ agbaye to wa lọdun 2022.
Ẹwẹ, ọjọ Aiku to kọja ni Manchester City koju Arsenal ni ifẹsẹwọnsẹ to maa n waye ṣaaju ibẹrẹ saa tuntun ṣugbọn Man City lulẹ lẹyin ti Arsenal na wọn ni ami ayo mẹrin si ẹyọkan ninu pẹnarity.
Amọ njẹ o ṣeeṣe ki Arsenal gba ade Premier League mọ Manchester City lọwọ ni saa bọọlu 2023/2024 yii?
Ipade dori papa!















