Tinubu fi ọ̀rọ̀ ìtùnú ránṣẹ́, bí aṣọ́lé Super Falcon ṣe bú sẹ́kún torí ìjákulẹ̀ sọ́wọ́ England

Lauren tẹ Alozie mọlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ agbabọọlu obinrin nilẹ England ti ja Super Falcons Naijiria kuro, ni idije ife agbaye awọn obinrin to n waye ni Australia.

England lo lu Super Falcons pẹlu ami ayo mẹrin si meji ni ipele Penalty lowurọ ọjọ Aje.

Ijakulẹ yii lo waye bi o tilẹ jẹ pe Super Falcons lo fakọyọ julọ lati ibẹrẹ pẹpẹ ifẹsẹwọnsẹ naa, nitori pe se ni England n tiraka pupọ lati gbera.

Anfaani miran ti Naijiria tun ni, ni igba ti adari ayo fun agbabọọlu England, Lauren James gba kaadi pupa, lẹyin to tẹ agbabọọlu Naijiria, Michelle Alozie mọlẹ ni ogoro ẹyin lasiko ti ayo wọ iṣẹju mẹtadinlaadọrun.

Ni bayii, England ti bọ si ipele quarter final idije naa.

Aarẹ Tinubu fi ọrọ itunnu ransẹ si Super Falcons

Ẹgbẹ agbabọọlu England si ni yoo koju Colombia tabi Jamaica ni ipele to kan.

Bi wọn ṣe fidi rẹmi yii ko dun mọ awọn agbabọọlu Super Falcons ninu rara.

Koda, ẹkun ni aṣọle wọn, Nnadozie bu si.

Ṣugbọn ṣa, aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, ati awọn ọmọ Naijiria kan ti gboriyin fun ikọ agbabọọlu naa fun bi wọn ṣe fakọyọ.

Ninu ikede to fi sita loju opo Twitter rẹ, Aarẹ Tinubu sọ pe awọn agbabọọlu obinrin naa ṣoju Naijiria daadaa pẹlu iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lori papa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post