Ọlọ́pàá, òṣìṣẹ́ FRSC àti LASTMA tó n gbà rìbá lójú pópó kó sí pańpẹ́ òfin

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police Command
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti ṣe afihan awọn janduku agbero to n gba owo loju popo lọwọ awọn ọlọkọ nla ati awakọ mii lagbegbe Mile 2.
Yatọ si awọn eeyan mẹẹdogun ti ọwọ wọn tẹ la tun ri awọn agbofinro ọlọpaa,oṣiṣẹ ajọ ẹsọ alaabo oju popo FRSC to n dari lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko Lastma.
Ọlọpaa mẹta, oṣiṣẹ FRSC kan ati oṣiṣẹ Lastma ni wọn fihan pe wọn n lẹdi apo pọ pẹlu awọn agbero lati maa gba owo lọwọ awọn awakọ.
Benjamin Hundeyin to jẹ alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Eko sọ pe kọmiṣana Eko Idowu Owohunwa lo paṣẹ kawọn ọlọpaa tọ pinpin awọn alaburu to n gba owo lọna aitọ lọna Mile 2.
Bawo ni ọwọ palaba awọn agbofinro to di arufin naa se segi?
Nigba to n salaye bi akara awọn agbofinro to sọ ara wọn di arufin naa se tu sepo, Hundeyin ni ikọ olutọpinpin kan ti kọmisana ọlọ̀pa ni Eko gbe kalẹ lo mu wọn.
Igbakeji Kọmisana ọlọpaa, Fatai Tijani, si lo dari ikọ atọpinpin naa.
Hundayin ni Idowu Olorunwa, tii se Kọmisana ọlọpaa ni Eko lo sagbekalẹ ikọ naa, to si fun wọn ni asẹ lati sewadi naa.
"Ojuse igbimọ naa ni lati maa tọpinpin awọn ibudo tawọn eeyan mẹnuba bii agbegbe ti isẹ ibi ti n waye.
Igbimọ naa, to bẹrẹ isẹ rẹ lọjọ Ẹti to kọja, ni ọpọ awọn ọga agba ọlọpaa wa ninu rẹ.
Agbegbe Mile 2 si ni wọn kọkọ morile nitori ibẹ la gbọ pe iwa gbigba riba pọ si julọ."
Hundeyin wa fọwọ gbaya pe ikọ agbofinro naa yoo tẹsiwaju ninu isẹ akin to n se lati pinwọ gbigba riba nipinlẹ Eko lai fẹ mọ bi awọn eeyan ti ọwọ tẹ ti kanka to.















