Inú bàbá mi kò dùn bí mo ṣe bọ́ aṣọ lórí pápá - Asisat Oshoala

Asisat Oshoala

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajúmọ̀ agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà ní obìnrin Asisat Oshoala ti ní inú bàbá òun kò dùn sí ọ̀nà tí òun gbà láti fi ìdùnnú òun hàn lẹ́yìn tí òun jẹ góòlù níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó bá kọjá.

Ní ọjọ́bọ̀ ní ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcons kojú akẹgbẹ́ wọn láti orílẹ̀ èdè Australia níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé àwọn obìnrin tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè Australia àti New Zealand.

Níbi ìdíje náà ni Asisat Oshoala ti bọ́ aṣọ rẹ̀ lẹ́yìn tó gbá góòlù sáwọ̀n ilé orílẹ̀ èdè Australia láti sọ góòlù náà di mẹ́ta sí ẹyọ̀kan.

Ìgbésẹ̀ Asisat Oshoala yìí sì di ohun tí ó fa awuyewuye lórí ayélujára nítorí ìgbésẹ̀ rẹ̀ yìí.

Bí àwọn kan ṣe ń kan sáárá sí Asisat Oshoala ni àwọn kan ń bu ẹnu àtẹ́ lu pé kò yẹ kí ó bọ́ aṣọ rẹ̀ kó sì máa fi ara rẹ̀ hàn.

Asisat fúnra rẹ̀ náà wá fi sórí Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì pé bàbá òun wà lára àwọn tí inú wọn kò dùn wí pé òun bọ́ aṣọ òun lásìkò náà tí òun jẹ góòlù náà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú bàbá òun kò dùn síbẹ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àkójọ àwọn nǹkan ìgbà ló ń jẹ́ ayé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ Asisat sì ti ń kan sáárá si wí pé àwọn ma ba bẹ bàbá rẹ̀ pé inú àwọn dùn sí góòlù tí ó jẹ náà.

Ṣáájú ni Asisat ti fi ìgboyà hàn pé ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà táwọn obìnrin ti ṣetán láti fi han gbogbo àgbáyé pé àwọn kẹ̀rẹ̀ rárá tó bá ti di ọ̀rọ̀ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.

Orílẹ̀ èdè Republic of Ireland ni Nààijíríà yóò tún kojú níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn mìíràn tó ń bọ̀.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post