Wo àwọn orílẹ̀ èdè tí ológun ti gbàjọba láìpẹ́ yìí

Awon ologun to gbajoba ni Niger

Oríṣun àwòrán, AFP

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ti ṣe ìdádúrò gbogbo àwọn ètò ìbojú àánú wo ni èyí tí wọ́n ń ṣe ní Niger lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà.

Ní ọjọ́rú ni àwọn ológun gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Mahomed Bazoum lẹ́yìn tí wọ́n se mọ́lé.

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní kò dín ní ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́rin ó lé díẹ̀ tó nílò ohun ìrànwọ́ ní Niger báyìí èyí tó jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlékún sí iye àwọn tó nílò rẹ̀ ní ọdún 2017.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi léde ní ó ṣeéṣe kí àwọn tí kò rí oúnjẹ jẹ ní orílẹ̀ èdè náà ti wọ mílíònù mẹ́ta láàárin oṣù Kẹfà sí oṣù Kẹjọ ọdún yìí.

Ẹ̀wẹ̀, igbákejì Ààrẹ Amẹ́ríkà, Kamala Harris bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ fífi ipá gba ìjọba ní orílẹ̀ èdè Niger nígbà tó ń bá Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu sọ̀rọ̀.

Àtẹ̀jáde kan láti iléeṣẹ́ Ààrẹ Amẹ́ríkà ní Kamala Harris ní gbogbo àjọṣepọ̀ tó ń wáyé láàárín Niger àti Amẹ́ríkà kò ṣẹ̀yìn bíbọ̀wọ̀ fún ìjọba àwaarawa.

France àti Amẹ́ríkà ti wá pè fún títú Bazoum sílẹ̀ ní kíákíá, kí wọ́n sì dá orílẹ̀ èdè náà padà ṣètò ijoba àwaarawa.

Ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní Niger yìí ni ẹ̀kẹsàn-án irú rẹ̀ tó máa wáyé ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àti àárín gbùngbùn Áfríkà rèé láàárín ọdún mẹ́ta.

Àwọn orílẹ̀ èdè tí ìdìtẹ̀gbàjọba ti wáyé láìpẹ́ rèé:

Burkina Faso

Nínú oṣù Kìíní ọdún 2022 ni àwọn ológun gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Roch Kabore ti Burkina Faso.

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni pé kò mójútó ìwà ìgbéṣùmọ̀mí àwọn alákatakítí ẹ̀sìn tó ń wáyé ní orílẹ̀ èdè náà tó.

Ẹni tó ṣáájú ìdìtẹ̀gbàjọba náà, ọ̀gágun Paul-Henri Damiba jẹ́jẹ̀ẹ́ láti dá ètò ààbò orílẹ̀ èdè náà padà sí bó ti yẹ àmọ́ níṣe ni ètò ààbò náà tún burú si.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́jọ tí ọ̀gágun Damiba gba ìjọba ni ọ̀gágun Ibrahim Traore tún fipá gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀ nínú oṣù Kẹsàn-án.

Mali

Àwọn ológun lábẹ́ ìdarí Assimi Goita fipá gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Ibrahim Boubacar Keita nínú oṣù Kẹjọ ọdún 2020.

Ìdìtẹ̀gbàjọba náà wáyé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ̀hónúhàn ti wáyé lórí ètò ààbò àti àbọ̀ ètò ìbò sílè aṣòfin orílẹ̀ èdè náà tó fi mọ́ ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdúnkòkò láti àwọn orílẹ̀ èdè tó jẹ́ alámùúlétì Mali, àwọn ológun gbé ìjọba padà fún àwọn alágbádá láti ṣètò ìdìbò láàárin ọdún kan àbọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, ìjà mìíràn tún wáyé láàárín àwọn tó dìtẹ̀ gba ìjọba náà tí wọ́n sì tún dìtẹ̀ gba ìjọba fún ìgbà kejì nínú oṣù Karùn-ún lọ́dún 2021.

Ìrètí wà pé nínú oṣù Kejì ọdún 2024 ni ètò ìdìbò sípò Ààrẹ yóò wáyé ní Mali láti dá orílẹ̀ èdè padà náà sétò ìjọba àwaarawa lẹ́yìn tí àjọ ECOWAS ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí gbogbo òfin tí wọ́n fi dè wọ́n.

Chad

Ní inú oṣù Kẹrin ọdún 2021 ni àwọn ológun gba ìjọba Chad lẹ́yìn tí wọ́n pa Ààrẹ Idriss Deby nígbà tó lọ ṣe àyẹ̀wò àwọn ológun tó ń kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí ní ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè náà.

Nínú òfin Chad, ẹni tó bá jẹ́ olórí ilé aṣòfin ló yẹ kó gba ipò Ààrẹ lẹ́yìn ikú Ààrẹ tó wà lórí ipò àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀ àwọn ológun tu ilé aṣòfin náà ká.

Ọ̀gágun Mahamat Idriss Deby tó jẹ́ ọmọ Ààrẹ tí wọ́n pa ọ̀hún ni wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí adélé, pé kó sì ṣe ètò ìdìbò láti yan Ààrẹ alágbádá láàárín ọdún kan àbọ̀.

Ìdìtẹ̀gbàjọba náà dá ogún sílẹ̀ ní N'Djamena, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè náà kí àwọn ọmọ ogún tó pa iná rẹ̀.

Guinea

Ọ̀gágun Mamady Doumbouya fipá gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Alpha Conde nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2021.

Ọdún kan ṣáájú ìgbà náà ni Conde ṣe àyípadà òfin orílẹ̀ èdè Guinea láti fi ààyè gba láti díje dupò Ààrẹ fún ìgbà kẹta àmọ́ èyí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri orílẹ̀ èdè náà.

Doumbouya di Ààrẹ fìdí ẹ tó sì ṣe ìlérí láti dá ìjọba padà fún alágbádá láàárín ọdún mẹ́ta.

Láti ìgbà náà, ní oṣù kìíní ọdún 2023 ni ìjọba ológun ọ̀hún ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àgbékalẹ̀ ètò láti gbé ìjọba fún alágbádá.

Àmọ́ àwọn alátakò ni àwọn ológun náà kò ì tíì gbé ètò kankan kalẹ̀ láti fi ṣètò ìdìbò tí wọn yóò fi gbé ìjọba kalẹ̀