Ọ̀wọ́n owó epo àti gáàsì ń bọ́ bí pàṣípààrọ̀ Naira ṣe di ọ̀lẹ níwájú Dọ́là

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Se ni awọn ọmọ Naijiria n kaya soke bayi pe bawo ni igbe aye awọn ko se ni buru ju bo se wa tẹlẹ nitori ọwọn gogo ounjẹ.
Akọtun ikayasoke yii si lo n waye nitori ipo ẹyin ti pasipaarọ owo Naira ilẹ wa wa si owo dọla kan.
Ni ọja pasipaarọ awọn kọrẹnsi agbaye to waye lana Ọjọbọ, se ni agbara owo Dọla ilẹ Amẹrika n lọ soke, ti agbara owo Naira ti Naijiria si n ja wa silẹ.
Ni Ọjọru ijẹta, N917 ni wọn fi n se pasipaarọ fun ẹyọ Dola kan dipo N850 ti wọn fi n ra dọla kan ni bii ọsẹ kan sẹyin.
Idi si ree ti awn eeyan se n bẹru pe pasipaarọ owo Naira si Dọla to gbẹnu sọke yii yoo tun se akoba nla nla fun eto ọrọ aje atawọn ọwọn gogo eroja.
Owo epo pẹtirolu, Disu ati gaasi yoo tun gbẹnu soke
Ẹgbẹ awọn alagbata eporọbi, IPMAN, ti sọ pe o ṣeeṣe ki iye ti wọn n a lita epo bẹtiro ati afẹfẹ gaasi tun lọ soke si.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Chinedu Okoronkwo sọ pe bi Dọla ba ṣe n gbẹnusoke, naa ni owo epo yoo lọ soke.
O ni awọn o ri Naira paarọ si Dọla ni awọn banki, owo gọbọi si ni awọn ileeṣẹ mii to n ṣe paṣipaarọ owo n gba lọwọ awọn lati sẹ Naira si Dọla.
Bakan naa ni alaga ẹgbẹ IPMAN nipinlẹ Kano, Bashir Dan Mallam, sọ fun BBC pe niṣe ni awọn ile epo n da owo papọ ra ọkọ epo kan ṣoṣo, dipo bi ẹnikọọkan ṣe n da a ra odindi ọkọ tẹlẹ.
“Ẹnu wo la fẹ ẹ fi sọ iye lita tuntun fun awọn ọmọ Naijriia? O dabi i pe titi pa ni kaluku yoo ti ile epo rẹ pa, tao si ma a wo oju ọlọrun.”
Ti iye ti wọn n ta lita epo kan ba tun fi lọ soke si ju 617 Naira ti wọn n ta a lọwọlọwọ, ko si ẹni to ti i le sọ iye ti wọn o fi kun.
Ninu iroyin miran, ẹgbẹ awọn alagbata afẹfẹ idana gaasi na ti sọ pe bi paṣipaarọ Naira si Dọla ṣe wọn si, le mu ki owo iye ti wọn n ta gaasi naa pọ si.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Olatunbọsun Oladapo, to sọ ọrọ naa fun awọn akọroyin nipinlẹ Eko l’Ọjọbọ sọ pe bi awọn ko ṣe ri Dọla fi ra ọja, ati iye ti wọn n ko gaasi wọle ṣe wọn si i, le ṣe okunfa tita gaasi ni ọwọn ti yoo ba fi to ọsẹ to n bọ.















