Ẹ yé gba owó orí lórí nǹkan oṣù wa láti ipasẹ̀ owó páàdì, ìṣẹ̀dá tiwa ni - Àwọn obìnrin fọ́nmú

Oríṣun àwòrán, TOKO MASEMOLA/CHANGE.ORG
Iwadii BBC kan ti ṣafihan bi awọn obinrin Ghana to n gba owo osu to kere julọ ṣe n na dọla kan ninu dọla meje ti wọn ba ri lori rira paadi nkan oṣu.
Orileede meje ni iwadii yi kan si lati mọ bi nkan ṣe ri pẹlu rira paadi.
A ṣagbeyẹwo owo oṣu to kere julọ nibẹ taa si wo iye ti wọn n ta paadi towo rẹ kere julọ.
Ghana jẹ ilẹ ti nkan yi rọju julọ amọ lawọn orileede to ku, rira paadi yi ko rọrun ti eleyi si jẹ nkan tawọn ajọ ajafẹtọmọniyan n gbero lati mu iyipada ba.
"Mo ni ibalopọ pẹlu ọkunrin to fẹ fun mi lowo lati ra paadi"
A o fi arabinrin Joyce ẹni ọdun mejilelogun orileede Ghana kan ṣe n ra paadi lasiko to ba nilo rẹ se apẹrẹ.
''Ẹni to ṣetan lati ran mi lọwọ n beere ibalopọ ko to le fun mi lowo.
Mo ni lati gba fun nitori mo nilo paadi loṣooṣu''
Ninu orileede mẹfa ti BBC kan si, ida mẹta si mẹtala ninu ọgọrun (3-13%) owo oṣu lawọn obinrin fi n ra paadi nkan oṣu idi meji to ni ẹyọ paadi mẹjọ ninu.
Afikun owo ori ti ijọba gbe le yii mu ki owo paadi lọ soke, tawọn obinrin si ṣe iwọde niwaju ile aṣofin lati tako igbesẹ ọhun loṣu kẹfa ọdun yi.

Oríṣun àwòrán, AMA PRATT, OBAASIMA FOUNDATION
Nigba ti ipa Joyce ko ka rira paadi, o bẹrẹ si ni lo iwe inudi taa mọ si toilet paper.
Nigba ti eleyi ko ran nkan to nilo, o pada si fifi ibalopọ gba owo ti yoo fi ra paadi.
Kyce nikan kọ lo n koju iṣoro yi.
BBC ṣe agbelewọn iye owo oṣu to kere julọ ni afiwe lorileede mẹsa an.
A wo owo yi pẹlu iye ti wọn fi n ra paadi taa si ri wi pe awọn paadi ti o wa lori igba ni Ghana lo wọn julọ ni afiwe tawọn orileede akẹgbẹ rẹ.

Bi a ba ṣe afiwe atẹ taa fi soke yi, a o ri pe awọn ọmọ obinrin ni Ghana n na iye owo to pọju ti akẹgbẹ wọn ni USA tabi UK lori rira paadi.
Francisca Sarpong Owusu, oniwadii kan ni ajọ Centre for Democratic Development CDD ni Ghana sọ pe akisa ti wọn tẹ nkan si lawọn ọpọ obinrin n lo ni Ghana.
Idi ni pe ipa wọn ko ka rira paadi yi.
Kaakiri agbaye si ni penija yi wa.Kii ṣe Ghana nikan.
Gẹgẹ bi banki agbaye ti ṣe sọ,obinrin 500m lagbaye ni ko lanfaani lati le ri nkan eloo paadi ti wọn yoo fi ṣe nkan oṣu.
Bẹẹ naa lo ni ko si ipeye awọn ohun amayedẹrun imọtoto bi omi ati ile igbọnsẹ ojulowo.
Ki ni igbiyanju tawọn ajafẹtọmọniyan n gba nipa yiyọ owo ori lori paadi?
Ọna kan gboogi tawọn ajafẹtọmọniyan sọ pe o le mu ki ipese paadi rọrun ni yiyọ owo ori lori nkan eelo yi fawọn obinrin.
Owo ori paadi jẹ owo ti ijọba fi le iye owo paadi ati awọn nkan eeloitọju ara mii fawọn obinrin.
Awọn ajafẹtọmọniyan sọ pe ijọba ṣi n foju nkan amuyangan wo awọn nkan eelo obinrin nipo nkan koṣemani.
Eyi lo mu ki owo ori awọn nkan eelo yi jẹ owo gọbọi bi ti awọn nkan meremere tawọn olowo n ra.
Lọpọ igba owo awọn ọja yi a maa wọn ju nkan mii lọ.
Kenya ni orileede Africa to kọkọ yọ owo ori yi lori paadi ati nkan eelo obinrin mii lọdun 2004.Lọdun 2016 o tẹsiwaju lati yọ owo ori lori awọn nkan eelo ipese paadi ati nkan mii fun awọn obinrin.
Toun ti eleyi awọn ajafẹtọmọniyan obinrin ṣi lawọn fẹ ki owo ori yi kere ju bẹẹ lọ.
Ni South Africa Nokuzola Ndandwe to jẹ ajafẹtọmọniyan nipa itọju ara obinrin ti n ja fun mimu adinku ba iye owo ori paadi lati ọdun 2014.
Ni oṣu Kẹrin 2019 o jaja ri aṣeyọri diẹ nipa ikede ijọba to lawọn yoo yọ ida 15% to wa lori paadi rira ti wọn si tun kede ipese paadi ọfẹ lawọn ile ẹkọ ijọba.















