Ìdí márùn ún rèé tí iye owó Naira sí Dollar fi ń peléke si

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọpọlọpọ ibeere to wa ni ọkan ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ni idi ti iye owo Naira si Dollar ṣe n peleke si.

Awọn ibeere yii tọ lati bere ni asiko nitori ọwọngogo to gbode to si n waye si.

Eyi ti bẹrẹ lati Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹfa, ti owo dollar si n goke si ni ojojumọ, ti eyi si mu idaamu ba awọn ọrọ aje nitori awọn eniyan ma n ra awọn nkan wa lati oke okun ju awọn ohun ti wọn n lo ni abẹle lọ.

Awọn idi ree ti iye owo naira si Dollar fi n peleke si.

Adinku ti ba iye owo Dọla to n wọle si apo isuna Naijiria ju ti tẹlẹ lọ

Ohun akọkọ to n fa ki naira maa kere si Dola lojoojumọ ni pe iye owo dọla to wa ni apo iṣuna Naijiria ti kẹrẹ si ti tẹlẹ lọ.

Ki ijọba tuntun yii to mu ayipada ba iye owo dọla si Naira, banki apapọ Naijiria ni awọn eniyan ma n lo lati fi san owo ileẹkọ ni oke okun ati lati duna dura fun idokowo ni oke okun.

Akọsilẹ ti CBN gbe jade fihan pe ida mẹjọ ni iye owo to n wọle lati ilẹ okeere si Naijiria fi dinkun ju ti ọdun to kọja lọ.

Iye owo dollar to n wọle kere si eleyii to n jade

Ohun ikeji ni pe iye dola to n wọle si Naijiria kere si iye owo naira to n jade.

Eyi tumọ si pe dola ko wọle to bo ti yẹ si ọrọ aje Naijiria, afi eleyii to n jade pọju lọ.

Ohun to n fa eleyii ni pe awọn owo to n wọle lati oke okun si Naijiria ti kere lati igba ti Banki Apapọ Naira ti gbe awọn aṣẹ tuntun lede, eleyii to mu idọgba ba tita owo dola ni banki ati awọn ti kii ṣe ti banki.

Igbesẹ tuntun ti CBN gbe jade

Awọn igbeṣẹ tuntun ti Banki apapọ Naijiria,CBN gbe jade lati Ọjọ Kẹrinla, Osu Kẹfa, ọdun 2023 ti mu ki owo naira kere si dola lati igba naa titi di asiko yii.

Lara awọn igbeṣẹ naa ni lati mu idọgba ba iye ti awọn eniyan n ra owo ilẹ okeere ni banki ati awọn ibomiran ti kii se banki amọ ti wọn ti n ta awọn owo ilẹ okeere.

Nigba naa lọhun, iye ti wọn n ta owo ilẹ okeere ni CBN yatọ si iye ti wọn n ta ni awọn ibomiran, amọ igbeṣẹ tuntun CBN naa mu ki banki apapọ naa yọ gbedeke kuro, to si mu ki idọgba de ba wọn.

Ileri aarẹ Tinubu

Iye ti wọn n ta owo dola ni banki apapọ ti o fa alafo laarin ti banki ati iye ti awọn onisọwọ dola n ta fi aaye silẹ fun iwa magomago ati ajẹbanu ni ẹka naa.

Aisi otitọ ni ẹka naa lo mu ki aarẹ Tinubu, Banki apapọ lagbaye, ajọ IMF ati awọn ajọ miran ni agbaye bu ẹnu atẹ lu ọna ti CBN n gba tẹlẹ naa.

Wọn ni eyi n mu ki awọn oludokowo lati ilẹ okeere sa si ẹyin fun Naijiria nitori aidọgba iye owo naira naa.

Amọ ayọkuro naa yoo fun awọn oludokowo ni anfaani lati duna dura ni iye to wu wọn, ti yoo si ṣe anfaani fun ọrọ aje wọn.

Eyi mu ki ọwọngogo ba owo dola, ti awọn eniyan si n raa ni iye to lee kan ni leegun ẹyin.

Ẹrọngba ọna tuntun CBN

Ohun ti ijọba fẹ ni lati mu adinku ba magomago to n waye ni ẹka banki ni Naijiria lọna ati mu owo wọle si Naijiria ni abẹle.

Amọ bi iye owo to n jade ṣe pọju eleyii to n wọle yoo mu ifaṣẹyin diẹ ba eto naa.

Ni oju ọja ni iye owo ti wọn n ta dọla goke si N930, eyi to peleke si ju N768 ti wọn raa ni Ọjọ Kẹtala, Osu Kẹfa, ọdun 2023.

Ki lo kan?

Awọn onimọ ni o ṣeeṣe ki ọwọngogo naa tẹsiwaju ju oṣu kẹfa, ti yoo si maa lọ si iwaju, lọ si ẹyin si.

Bakan naa ni wọn ni iru asiko yii ti waye ni ọdun 2016 si ọdun 2017, eleyii to mu ki iye owo naa wọngogo nigba naa lọhun.

Amọ atunṣe ti CBN ṣe nigba naa mu ki iye owo naa dọgba ti yoo si wale lati N520 si N360, nigba naa lọhun.

Amọ ni bayii o ṣeeṣe ko to bi ọdun kan si ọdun kan abọ, ki idọgba naa to le waye.