Ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Osun Osogbo ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀ – Adeleke

Gani Adams

Ilu Osogbo ni ipinlẹ Ọṣun mi títí pelu bí àwọn ónìṣese kakiri àgbáyé ṣe peju pesẹ láti se ayẹyẹ asekagba ọdún Ọsun Osogbo ti ọdún yìí.

Ataoja tí ìlú Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji Olanipekun àti àwọn olorí, ìjòyè àti àwọn ará ìlú gbogbo lo peju síbi ayẹyẹ Ọdún náà.

Ataoja tí ìlú Osogbo nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ ní àkókò tí ọdún Osun Osogbo dùn ju ni ti ọdún yìí pẹ̀lú bí ìjọba ipinle Ọsun se lọ́wọ́ sí ètò gbogbo, tí wọn si ṣe àdúrà fún onílé àti àlejò.

Gómìnà Ademola Adeleke àti ìyàwó rẹ náà ko gbeyin nibi ayẹyẹ ọhun pẹlu gbogbo àwọn oṣiṣẹ rẹ.

Gómìnà Ademola ni ìdàgbàsókè tó pọ yóò dé bá ojubọ Osun Osogbo àti ayẹyẹ ọdún naa pẹ̀lú àwọn nkan mèremère tí ìjọba tunbọ máa se láti gbé àṣà lárugẹ.

Ààrẹ Ona Kakanfo, Iba Gani Adams gbóríyìn fún ìjọba Ademola Adeleke fún ifọwọsowọpọ rẹ lórí ayẹyẹ Ọdun Osun Osogbo tó mú kí tí ọdún ó yàtò.

Gani Adams tún kilọ fún àwọn àṣẹbàjé tí wọn má ń lò àkókò ayẹyẹ ọdún náà láti ja àwọn àlejò àti onílé lólè láti dẹkùn ìwà ibajẹ náà.

O ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Oodua Peoples Congress, OPC, yóò ṣíṣẹ papọ pẹlu awọn eleto àbọ̀ tó kú ní ọdún to n bọ.

Ọdẹ ìbílẹ̀ 700 yóò pèsè ààbò bí àṣekágbá ọdún Osun Osogbo ṣe ń wáyé

Aworan

Ilu Oṣogbo ti n rọ kẹkẹ bayii loni aṣekagba ọdun Osun Osogbo ti yoo waye ni ilu Osogbo, ni ipinlẹ Osun

Awọn araalu, awọn oniṣeeṣe to fi mọ awọn alajo lo ma n pejọ sibẹ ni ẹgbẹlẹgbẹ wọn.

Awọn arinrinajo lati oke okun naa ko gbẹyin ni ibi ayẹyẹ naa, ti wọn si n wa lati wa wo ẹsin abalaye ni orilẹede Naijria.

Lara awọn to pejọ naa ni wọn wọ aṣọ funfun ti wọn si n to ni ọwọọwọ lọ si Ataọja.

Bakan naa ni awọn ọlọja ko gbẹyin nibẹ ti wọn si n ta awọn ohun meremere fun awọn araalu to ba fẹ ra.

Aworan
Aworan

Awọn onifa, babalawọ awọn wa nibẹ pẹlu aṣọ alaranbara wọn.

Ọṣẹ meji ṣẹyin ni ọdun oṣun Osogbo naa bẹrẹ, ti yoo si pari pẹlu ọdọbinrin Arugba ti yoo maa rin irinajo lọ si Ataoja.

Awọn oniṣẹṣẹ lọwọọwọ ni yoo pejọ pọ si ojubọ naa lati ṣe ajọyọ ọdun Osun Osogbo ọhun.

Aworan
Aworan

''Àwọn ọ́de 700 ni yóò pèsè ààbò''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọde to to ẹẹdẹgbẹrin ti wa ni igboro ilu Oṣogbo bayii lati pese aabo fun awọn ara ilu ni oni ọjọ aṣekagba ọdun Osun Osogbo to n lọ lọwọ.

Awọn ọlọde naa lo wa ni abẹ ẹgbẹ Nigeria Hunters and Forest Security Service ti ipinlẹ Osun.

Alaga awọn ọlọde naa, Ahmed Nureni ni awọn ọdẹ naa ni awọn ti fun ni imọ to tọ nipa iṣẹ ti wọn nilo lati ṣe ni oni.

Nureni fikun un pe awọn ọlọdẹ naa yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo miran lati pese aabo fun awọn araalu.

‘’Ati fun wọn ni imọ to to nipa eto aabo abẹnu, ti wọn yoo si jẹ ki eto ọdun Osun Osogbo naa lọ ni irọwọrọṣẹ.’’

Awọn ọdẹ naa wa rọ awọn araalu lati wa ni ibamu pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo.

Bakan naa ni wọn kilọ fun awọn ti wọn ba fẹ da wahala silẹ lati sọra fun iwa ọdaran naa.

Aworan
Aworan

Wọn kesi awọn araalu lati tẹle ofin ati ilana ki wọn si rin ni ọna to tọ ni asiko ọdun naa..

Awọn ẹṣọ naa rọ awọn arinrinajo to n bọ fun ọdun naa lati gbadun ara wọn, ki wọn si rin si iwaju rin si ẹyin bi o sẹ wu wọn lai si ibẹru.