Wo bí wọ́n ṣe yọ ọmọ ọdún mẹ́ta tó já sínú kànga

Odidi wakati mẹjọ ni awọn gende ọkunrin kan fi wa layika kọnga pẹlu ọpọlọpọ igbiyanju lati doola ẹmi ọmọ ọdun mẹta to ja sinu kanga
Kanga yii jin to mita mejila, ti omije si kun oju iya ọmọ pẹlu ireti pe wọn yoo ri ọmọ naa yọ.
Shivam Kumar lati Nalanda lorilẹede India, ni ila oorun Ipinlẹ Bihar lo n ṣere lẹgbẹ kọnga to wa ni ṣi ṣi, ko to jabọ sinu rẹ.
Lẹyin igbiyanju wakati mẹjọ, awọn olugbala ri ọmọ naa yọ sita laye.
Ni kiakia ni wọn gbe Shivam lọ si ile iwosan fun ayẹwo, to si ti n gba itọju.












