Ẹ wo aràn 8cm tí wọ́n bá nínú ọpọlọ arábìnrin yìí láàyè

Fun igba akọkọ lagbaye, awọn onimọ sayẹnsi ti yọ aran to to iwọn sẹntimita mẹjo(8cm) laaye ninu ọpọlọ arabinrin kan lorilẹede Australia.
Aran ọhun ti awọn oloyinbo n pe ni Worm ni wọn yọ kuro ni iwaju ori arabinrin naa lasiko ti wọn se iṣẹ abẹ fun ni agbegbe Canberra, ni ọdun to kọja.
Obinrin naa ni awọn dokita ni oun koju awọn ami ti koni lominu, ti wọn ko simọ ohun to le faa.
Arabinrin naa lo n pariwo inu didun, ikọ ati ki o maa laagun ni alaalẹ.
Awọn aisan ti wa mu ki o maa tete gbagbe nkan, ti o si ma banujẹ pẹlu aisan irẹwẹsi ọkan.
Awọn dokita ni oseese ki kokoro to w ani ọpọlọ naa ti wa nibẹ fun oṣu meji.
Bakan naa ni awọn onimọ kilọ fun awọn eniyan wi pe o ti n peleke si bayii ki awọn ẹranko maa fi ko aisan ran awọn eniyan.
Awọn onimọ se apejuwe rẹ gẹgẹ bi iru aisan ti wọn ko tii riri ni agbaye.
‘’Gbogbo awọn to w ani yara ti wọn ti se iṣẹ abẹ naa ni isẹlẹ ọhun b ani ojiji, ti wọn si salaye bi obinrin naa se ko iru iselẹ abami yii.
Bi Obinrin naa se ko aran naa ni yii

Oríṣun àwòrán, ANU
Aran ọpọlọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Phidascaris robertsi ni o wọpọ laarin ejo nla, ti wọn ko tii ri iru rẹ lara eniyan ri, paapaa lara awọn ejo ni wọn wọpọ ni agbegbe Australia.
Dokita onimọ nipa kokoro, Mehrab Hossain ni obinrin ni oun woye pe o ko aarun naa lẹyin to ewebẹ Warrigal greens, ti ejo ti tọsi to si tun ye ẹyin si.
Arabinrin naa ni wọn ni o lo ewebẹ yii lati fi dana ounjẹ, to si jẹ, ti eyi si fa aisan si lara.
Ọdun 2021 ni arabinrin naa ni wọn be lọ si ileewosan ni ọdun 2021, ti wọn si pe nkan wa ni iwaju ọpọlọ rẹ.
Amọ asiko ti wọn n se isẹ abẹ fun ni ọdun 2022 ni ọbẹ dokita naa kan nkan aramanda to n rin ni ọpọlọ rẹ naa.
Awọn onimọ naa ni aroko ni iru aisan yii n pa fun awọn eniyan nitori o ti n wọpọ bayii ki awọn eniyan maa ko aarun lati ara ẹranko.
Apẹrẹ rẹ ni Ebola, Coronavirus bii Sars ati Mers naa to n ti ara adan bọ si ara eniyan.















