Baale Magba Koso on Yoruba tradition: Àwọn nǹkan àbáláyé lóyẹ kí àwọn olóṣèlú máa fi búra tí wọ́n bá fẹ wọ ọ́fíìsì
Ọkan ninu awọn ọdun ilẹ Yoruba to lamilaaka ni agbaye ni ọdun Sango jẹ.
Aafin ọba ilu Oyo ni ipinlẹ Oyo ni Iwọ oorun guusu Naijiria ni ayẹyẹ yii ti maa n waye ni ọdọọdun.
Ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni ayẹyẹ ọdun Sango miiran tun waye fun igba keji ni ilu Oyo lẹyin ti Oba Lamidi Adeyemi Kẹta darapọ mọ awọn Babanla rẹ lọdun 2022.
Baalẹ Magba Koso ninu alaye to se pẹlu BBC Yoruba ṣalaye pe ayẹyẹ ọdun Sango kii ṣe ọdun kekere to yẹ ki awọn eniyan fọwọ yẹpẹrẹ mu rara.
O kọminu pe ọpọ ọmọ Yoruba lo ti sọ aṣa ati iṣe wọn nu nitori wi pe wọn maa kaṣa awọn oyinbo to si jẹ pe ọpọ awọn oyinbo lati okeere n wa si ilu Oyo lati wa kọ nipa Sango.
O tẹsiwaju pe o ṣeni laanu pe awọn ọmọ Yoruba ti awọn oyinbo n wo gẹgẹ bi awokọṣe n fi oju tẹmbẹlu aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.

O ṣalaye lati ọdun 2014 ni awọn eniyan lati orilẹ ede Brazil ti wa n kẹkọọ nipa bibọ Sango ni ilu Oyo leyii to si ti n mu ẹsin naa gbooro si.
Magba Koso tun parọwa si awọn onimọ nipa ẹkọ iwe lati gbaruku awọn ohun to jẹ ohun abalaye lati le mu iṣẹṣe maa gbooro si.
O tẹsiwaju pe aisi ẹkọ imọ iwe to bẹẹ lara awọn to n ṣe ẹsin ibilẹ lo jẹ ki awọn kan maa fi oju tabuku tabi ki wọn maa foju idọti wo o.
Bakan naa lo tun parọwa si awọn oniṣẹṣe pe ki wọn maa tọ awọn ọmọ wọn ni ile ẹkọ ki wọn le tun mu ọna igbalode wọ ẹsin naa.
Ofi kun pe ẹsin ibilẹ jẹ ẹsin ootọ idi niyi ti ọpọ awọn oloṣelu ti wọn n wọ dipo oṣelu mu kii fẹ fi awọn ohun abalaye bura nitori wọn mọ wi pe ti awọn ko ba ṣe otitọ lori ipo, awọn maa ri ija ohun ti wọn ba fi bura.
- 'Alaafin tuntun gbọ́dọ̀ mọ pàtàkì ìṣẹ̀ṣe nílẹ̀ Yorùbá'
- Ta ni Ọ̀gágun Brice Oligui Nguema adári tí ológun Gabon gbé ìjọba fún báyìí-
- Kí ni India ń wá lọ sí inú Oòrùn-
- Fact Check- Ṣé òótọ́ làwọn fídíò owó inú àpò tó ń jáde lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní Gabon àbí òfégè-
- Ìpín ìdíje Champions League jáde, Man City, Arsenal, Man Utd àti Newcastle mọ àwọn alátakò wọn