Ìpín ìdíje Champions League jáde, Man City, Arsenal, Man Utd àti Newcastle mọ àwọn alátakò wọn

Aworan lati ibi ayẹyẹ Uefa Champions League

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle United yoo ma koju ikọ Paris St-Germain, Borussia Dortmund ati AC Milan ni isọri F idije UEFA Champion League tọdun 2023-24.

Ọdun 2002-03 ni ikọ Newcastle United farahan kẹyin ninu idije Uefa Champions League, ti wọn yoo si maa koju awọn ẹgbẹ agbabọọlu agba ọjẹ.

Manchester United yoo ma wọ iya ija pẹlu Batern Munich, nigba ti alamuleti wọn Manchester City, ti wọn gba ife naa ninu oṣu karun un ma ninu isọri pẹlu ikọ RB Leipzig.

Ikọ Arsenal ati Sevilla wa ninu isọri kan na, ti Celtic ati Atletico Madrid yoo ma dana sun ara wọn.

Apapọ awọn Isọri

Isọri A: Bayern Munich, MANCHESTER UNITED, FC Copenhagen, Galatasaray

Isọri B: Sevilla, ARSENAL, PSV Eindhoven, RC Lens

Isọri C: Napoli, Real Madrid, Braga, Union Berlin

Isọri D: Benfica, Inter Milan, Salzburg, Real Sociedad

Isọri E: Feyenoord, Atletico Madrid, Lazio, CELTIC

Isọri F: Paris St-Germain, Borussia Dortmund, AC Milan, NEWCASTLE

Isọri G: MANCHESTER CITY, RB Leipzig, Red Star Belgrade, Young Boys

Isọri H: Barcelona, Porto, Shakhtar Donetsk, Royal Antwerp

Idije ninu awọn isọri yoo ma bẹrẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan an wọ ọjọ kẹtala oṣu kejila, ti ipele aṣekagba yoo si ma waye lọjọ kinni, ọsu kẹfa ọdun 2024 ni paapa Wembley.