Adé eré 100m hurdles bọ́ lórí Tobi Amusan, Ó ní àgbò òun tó fẹ̀yìn rìn agbára ló lọ mú wá

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajumọ asare ori ọdan, Tobi Amusan ti ni oun yoo pada pẹlu agbara lọdun to n bọ lẹyin to lulẹ ni bi ere ije asafogi 100m hurdles nibi idije World athletics champiuonship lalẹ Ọjọbọ.

Danielle Williams ọmọ orilẹede Jamaica lo gba ade ereije asafogi 100m hurdles ni ibi idije naa to waye Budapest.

Amusan, ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin lẹyin ere naa, salaye pe awọn ilakoja ti oun n dojukọ ṣaaju idije naa kun ara oun to ṣokunfa ijakulẹ oun.

O wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ fun aduroti lasiko to ni isoro, o wa tun ṣe ileri pe oun yoo pada pẹlu agbara to yẹ lati se aseyọri.

Amusan ni oun yoo gba ami ẹyẹ oun pada lọdun to n bọ.

"Nnkan to le gan ni nítorí ko si ẹni to fẹran lati lulẹ sugbọn pẹlu gbogbo nnkan ti mo ti la kọja fun ọpọlọpọ oṣu, inu mi dun ibi ti mo ba de."

Williams, ẹni Ọgbọn ọdun lo bori ere ori ọdan 100m hurdles tọdun 2023, ti Jasmine Camacho sì wa ni ipo kejì pẹlu Kendra Harrison ni ipo kẹta

Ipo kẹfa ni Tobi Amusan gbe ninu ere ori ọdan 100m ti awọn obinrin.