'Alaafin tuntun gbọ́dọ̀ mọ pàtàkì ìṣẹ̀ṣe nílẹ̀ Yorùbá'

Aworan Apoti Alaafin

Oríṣun àwòrán, Others

O ti le ni ọdun kan bayii ti Alaafin Oyo, Iku baba yeye, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta waja.

ọpọeeyan lo si leri nigba naa pe ko ni pẹ pupọ ti Ọba tuntun yoo fi jẹ l'ode Ọyọ nitori pataki rẹ nilẹ Yoruba.

Nibayii, ipe ti wa n jade si gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde pe ko tete jawe sobi lori rẹ.

Ẹgbẹ onisẹṣe kan, Iṣẹṣe Welfare Association ni ẹni to ni to ni imọ, ti yoo si tun bu iyi fun Isẹṣe ni ilẹ Yoruba ati oke okun ni ki wọn yan si ipo naa

Ninu Atẹjade kan ti wọn fi sọwọ si awọn akọroyin niluu Ibadan, ẹgbẹ naa ni o ṣe koko ki Alaafin tuntun naa jẹ awokọṣe fun Ilẹ Yoruba gẹgẹ bi Alaafin to waja.

Olori ẹgbẹ naa Aderemi Ifaoleepin ati Akọwe ẹgbẹ, Ifagbenuola Popoola ni o ṣe koko ki Gomina Seyi Makinde ati Afọbajẹ jara mọ yiyan Alaafin tuntun nitori pe ipo to se pataki si ilẹ Yoruba ni ipo Ọba naa.

'Alaafin ti yoo bọwọ fun iṣẹṣe ni Ọyọmesi gbọdọ yan'

"A n kesi Oyo Mesi, ti wọn jẹ Afọbajẹ niluu Oyolati ri daju pe ẹnikẹni ti wọn yoo ba yan gẹgẹ bi Alaafin jẹ eeyan to ni imọ nipa Isẹṣe ati asa ilẹ Yoruba

"Gomina Seyi Makinde ti yoo gbe ọpa asẹ fun Ọba tuntun gbọdọ ri daju pe eeyan ti yoo ilọsiwaju asa ati isẹṣe Yoruba ni wọn Ade Ọba fun .

"A wa rọ ẹnikẹni ti wọn kede gẹgẹ bi Alaafin tuntun lati ni lọkan pe Ipo Alaafin jẹ ipo to gbọdọ ni ibọwọ fun isẹṣe Ilẹ Yoruba."

Bakan ni ẹgbẹ yii kan sara si Ijọba ipinlẹ Oyo ati awọn Afọbajẹ ilu Isẹyin fun bi wọn se kede Ọba tuntun fun ilu Isẹyin.

Wọn wa rọ Ọmọọba Sefiu Olawale Oyebola lati fọwọsowọpọ pẹlu Isẹse Yoruba lasiko to wa ni ori oye.